YOSM / dev.tsv
Iyanuoluwa's picture
Upload 4 files
4b2f1ee
raw
history blame
35.9 kB
yo_review sentiment
Ó mà dára o. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni sinimá yìí tí dùn. N kò tíì rí àṣìṣe kankan. Lóòótọ́, ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ rí bákan àmọ́ wón ṣe fẹ́ kó rí nìyẹn. Ata kéré iyọ̀ dùn ún ni fíìmù yí. Mo gbà yín níyànjú kí ẹ lọ wò o. positive
KOB ni ó gbégbá orókè fún èmí laarin àwọn eré orí ìtàgé tó kù lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí. Eré náà fí òṣèlú ṣe rí lóayé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. positive
Sinimá to lè kenkà lèyí. Mà á fi ọwọ́ rẹ̀ sọ àyà fún ẹnikẹ́ni láti wò ó. positive
moféràn eré yí mà á gbádùn kin ma wó fún ọ̀pọ̀lopọ̀ odún tí ó nbò àti òrò àbásọ tí ó ma ń múwá Eré ṣíṣe lo létò láìsí orin aládùn, ó ṣe gbàgbó. Ju gbogbo ẹ lo, eré na dára, ó gba àsìkò mi. positive
Mo féràn eré yìí positive
FÍÌMÙ TO GBÁMÚSÉ PẸ̀LÚ ORÍYÍN DIẸ́ positive
Ìtàn to lewa ti o ṣàfihàn àṣà ilẹ Nàìjíríà. Ìtàn náà yàtọ ti o sí nira lati lè mọ ìparí rẹ gẹgẹ bi awọn eré Naijiria miiran. Agbọdọ wo ni eré náà positive
Eré tí èèyàn gbọdọ̀ wò ni, ìtàn tí ó dára tí wọ́n sì ṣe dáradára pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn òṣèré Hollywood àti Nollywood. Mo gbádùn-un rẹ̀. positive
POV tuntun Kì í ṣe irú sinima ilẹ̀ òkèèrè tí a mọ̀. Kì í ṣe pé ìgbéjáde rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìtàn tí a fẹ́ gbésókè nìkan, ó tún sàfihàn àṣà agbègbè tí a ti ṣe eré náà positive
Eré Citation ṣe iṣẹ gidi nígbàtí o ṣàfihàn ìgbàgbọ òṣèré pàtàkì àti bí wón se gbógun tó nígbà tí ó sàlàyé oun tí ó ṣẹlẹ̀ sí, bésìnì lákọ̀kọ́ó kò ye ni bóyá ìdájọ́ náà yóò ṣàfàní fún òṣèré náà Àbí yóò ṣe àkófún. positive
Nínú eré tó dàeni ti o tó yẹ kó jẹ́ ere tí à ń sáfihàn rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, a rí ìbáṣepọ̀ lásán to sì tẹ̀síwádi láàrin ọkùnrin àti obìnrin. positive
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a padà rí èyí tí ó dára. Láti ọwọ́ AYỌ̀ MÁKUN, eléyìí múná d’óko. Ó pá ẹ̀fẹ̀ gidi àti ìfẹ́ ọkàn papọ̀. Àgbọdọ̀wọ̀ ni fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà. positive
Fíìmù orílè-èdè Nàìjíríà tó dára jùlọ tí mo yí rí, fíìmù yìí yá ní lẹ́nu, alátiúdá púpọ àti alailọwaya. Mo fẹràn ni ìtàn náà se jẹ́ ti òde òní,tí o sí tún n'isẹ pelu òun tí o nlọ ni orílè-èdè Nàìjíríà lọwọ yìí, iṣẹ́ àrà ní . Alayé ní Ṣọlá Sobowale jẹ́ positive
Iṣẹ́ ọwọ́ tí ó fákọyọ: o jẹ́ tuntun, ó wà pẹ̀lú ìrora àti ìfọmọènìyànṣe positive
Ipele eré tó dára Orí mi wú si ipele eré yìí. Eré aládùn tó tún mo ní mólè. positive
Mo fẹ́ràn fíìmù yìí eré yìi ́jé eré tó dára púpọ̀ ó sì wù mí tí ó bá tẹ̀síwájú. Ẹ jọ̀wọ́, ìgbà wo ni ìpín kẹẹ̀ta àti ẹ̀kẹẹ̀rin yóò jáde? positive
Eleyii fi òtítọ́ múlẹ̀ bii àkọ́bí nínú ilé olówó áfíríkà. Eré tó fi wàhálà ti àwọn obìrin máá n kojú ní àwùjọ tí ọkùnrin jẹ́ ojúlówó ọmọ nì ìlu Afirika. positive
Ìtàn tó lágbára Eré yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ nínú. Zainab Balogun túmò ipa náà dáadáa. Tí o bá ti sọnù, ǹkan tí o nílò ni eré yìí, yóò sì tọ́ ẹ sónà padà sí ìlànà ọlọ́run. positive
Ere to ń ru ènìyàn nínú tó sì fà nílẹ̀ positive
Nípa ti ìmọ̀ ẹ̀ro, ohùn náà dára púpò, béè sì ni àwòrán yíyà yáàtọ̀ sí ti àtẹ̀yìnwá tí ó sì dára. Wọ́n ṣe àwọn ìran ìjà náà dáradára. positive
Fíìmù Nàìjíríà tí ó dára jù tí mo ti rí ní ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn rèé. Fíìmù gidi tí ó dìídì sọ nípa àṣà Nàìjíríà àti ilé ișẹ́ fíìmù rẹ̀ ni. positive
Irú ìtàn tí ó ń dani láàmú ṣùgbọ́n tí ó ń kóni ní papá móra wo ni èyí! Ìtàn yìí ń po ẹni nínú pọ̀ gan-an ni. Inú mi gan-an fún Eniìtàn, mi ò lè ṣàdédé fi ojú inú wo ohun tí ó làkọjá ní ìgbà èwe rẹ̀. Àyípadà rẹ̀ jọnilójú. Ìparí rẹ̀ fi eni tí Eniìtàn jẹ́ hàn, ìfihàn náà síì ṣe mí ní kàyéfì. Ó mú Fíìmù náà wá sí ìmọ̀sílára tí ó lé téńté ní ipele mìíràn. positive
Eré tó yani lénu, ìpinu dáradára àti ìtàn gidi. positive
Romper Stomper pèlú Eré lílọ̀ àti àsetán Fíìmù àsà orí awo tí a gbé jáde ní ọdún séyìn…Tí mo bá féràn Fíìmù Rpmper Stomper, ‘‘This is England,A Clockwork Orange’’… O máa féràn èyí àti ọ̀pọ̀;ọ̀pò tí a ṣe dáadáa…Eré àkọ́kọ́ ṣe àwọn òṣèré máa ń jáde láti èrírí wọn…Fíìmù tó tayọ…Mo féràn rè… ó dunni láti rí bí àwọn ènìyàn ṣe ń fi ojú kékeré wò ó nítorí wípé ó jáde láti ọwọ́ ènìyàn tuntun… è gbádùn re è. positive
O dára púpọ fún àwọn obìnrin àti àwọn ọkùnrin náà. Nínú Ayé tí ó pọndandan fún àwọn obìnrin láti ṣe ju arawọn lọ, tí wọn sì ni gbé jù bí wọ́n ti mọ̀ lọ, eré yìí jẹ́ gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ fún ìdánilékọ̀ọ́ nípa ètò ìṣúná tí o sí tún darí wọn sì Egbe ètò ìṣúná ti o dára àti ànfàní tí ó wà nínú ìserenílógo tí ó pẹ̀. Béèsìni, eré náà dún wò ó sí tún fakọyọ. Sùgbón o, orin inú eré nà kò dára tó. positive
Àwọn akọ̀nlọ̀ èdè tí wọ́n lò ma jẹ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu wa fún ọjọ́ pípé. A má má sọ́ láti rántí eré na taa wò. positive
Ó dára fún ìgbà àkọ́kọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀hun rẹ̀ já gaara díẹ̀, kò sí nnkan tuntun nínú eré náà. Ohun ni fíìmù àgbéléwò tó dá lórí Kérésìmesì ni Nàìjíríà. Ere yìí dùn díẹ̀. positive
Sinimá tí ó dára tí ó sì kọ́ni lọ́gbọ́n rere ni. Sinimá yìí dá lórí ọmọ ọkùnrin kan tí ó ń dàgbà tí kò sì fẹ́ káwọ́ gbera. Tí a bá wò ó, mo wòye pé sinimá yìí ń fi bí ati ń ṣe ní ilẹ̀ Adúláwò hàn ni àti bí àwọn ọmọdé ṣe ń kọ́ bí a ti ń ní ìtẹríba. positive
CITATION ṣe àfihàn ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí èyí tí ó pọ̀jú nínú àwọn ọ̀dọ́ wa, pàápàá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti pàápàá àwọn tí ó jẹ́ obìnrin. positive
Òṣèré obìnrin tí mo féràn jù Adesua Etomi Wellington ló gbé mi débi eré onípele yii, mi ò sì kà bá mó rẹ̀. Ìdùnnú ló jẹ́ láti ri eré ṣíṣe tó dára, àti eré kíko pẹ̀lú rírí i, gbogbo àwọn òṣèré ṣe dára dára, ẹ́písòdù kò kan le dá dúró. Ti ẹni Kéni bá ń wá eré gidi láti wò, o le ṣàṣìṣe láti wo arábìnrin to yàtò ti Naijiria yìí. positive
Ó ṣe ni láàánú, nítorí èyí le jẹ́ ìyanilẹ́nu púpọ̀ . Ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́, ó jẹ́ àkójọ pọ̀ wákàtí tí kò gbéwọ̀n positive
Ó mu mí mólè !!! Mo gbádùn rẹ. Èyí jẹ́ eré àgbéléwò tó dára púpò to jáde wá lá́ti inú àwọn fíìmù Hollywood . Mi ò fi àkókò mi ṣòfò rara. positive
Ó ga jù. Mo fi Ògún Nọ́líwuùdù gbá orí fún àkójọpọ̀ ère yìí. positive
Fíìmù to yanilenu Itan to rewa, siso daadaa ati sise daadaa. Gbogbo nkan lati ibi ti won ti se ere, kikun oju, awon osere, ede ati fifihan asa dara. Ku ise nKunle Afolayan positive
Eré yìí dára gan ó sì sée fii yangàn àti pé àṣeyọrí ńlá ni ó jẹ́. Eré orí ìtàgé yìí dára gan ni mo sì gbádùn wíwòo rẹ̀. Oun ìdárayá ní sinima yìí jé, gbogbo ìpele rẹ ní wọn ṣe iṣẹ takuntakun láti le mú kó wú ni lórí. Mo gbà pé mí ò fowó Jóná lórí sinimá àgbéléwò yìí. positive
Láì sí ijiyan rárá eré orí ìtàgé yìí ní ó tíì dáa jù nínú àwọn eré ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà positive
O dára sùgbọ́n ó rújú díè Mo féràn àdìtú nípa ìpànìyàn ti orílè-èdè Nàìjíríà. Àwọn ìsèlè da sùgbón ènìyàn tilè mọ ibi tí eré náà ń lọ àmọ́ mo ní ìfé síí eré náà. positive
Ó dùn eré yìí dùn láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. eré ṣíse náà dára gáan. positive
Ohun tí o jẹ́ pàtó láti jẹ ọmọ Nàìjíríà, Genevieve Nnaji kú iṣẹ́. Fíìmù tí ènìyàn gbogbo gbúdọ̀ wò, Naijiria saara rẹ,má tẹ̀síwájú. positive
Ìṣòro kan ṣoṣo positive
Lionheart jẹ́ fíìmù tí o lágbára tó sì fi ìbálòpọ̀ hàn dáradára ní ibi-iṣẹ́ mi orílè-èdè Nàìjíríà. Ó wá ní ọ̀nà òtítọ́, àsọtẹ́lẹ̀ gíga àti ní ìtọ́sọ́nà ní ye aláìlágbára nípasẹ̀ Genevieve Nnaji. Ṣùgbọ́n ní ọnà ìdákejì, iṣẹ́ ṣíṣe rẹ̀ kò jẹ lásán àti wípé o fi iṣẹ́ ìgbéga hàn fún òṣèré ati awọn òun èlò òṣèré. Fíìmù nàà jẹ́ oun ìwúrí. Yíò o dára láti yàn án fún ilé - ẹ̀kọ́ fíìmù,tí kò bá n se wipe wọ́n ṣe ní èdè gèésì. positive
Ìyànílenu!!! Eré yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn eré tí mo ti wò láyé. Mo fẹ́ràn rẹ̀!!! positive
Eré orí ìtàgé tí mo gbádùn wíwò rẹ ní, ìtàn eré náà dára púpọ̀ Ài mọ oun tókàn nínú eré yìí máa mú kí o fojúsọ́nà, lẹyìn ìgbà náà wàá tún rérìn lẹyìn ìgbà tó bá rí abajade iṣẹlẹ kan nínu eré yí. Àkókò tí mo fi sile lati wo eré orí ìtàgé kò sòfò dànù positive
Ere ònídàákúrekú ṣùgbọ́n àtúnṣe rẹ̀ ìbá dára fún ìtàn gidi. Mo gbóríyìn fún olùdarí ere yìí (Ramsey Nouah) àti ọ̀nà ìṣeré rẹ̀ positive
Eré orí ìtàgé yìí dára gan-an. Kòsí àbàwọ́n kankan bóti wù kó mọ. Gbogbo ènìyàn tó lọ́wọ́ sì fíìmù yìí gbìyànjú gan. Wọ́n sì mú orí mí wú pé orílè-èdè Nàìjíríà tèsíwájú nínú eré oríìtàgé positive
Ohun ìdùnnú ni láti rí sam dédè lójú pátákó ìṣeré àti lasi tún tí rí pé ó ṣì meré ṣe ibi kí bi to bá tí ri Stella Damascus, ó dá mi lójú pé omi ẹkún ma jáde lójú ẹ. Ko ti ẹ jọ pé ó ń dàgbà. positive
Pípé Kòṣemawo ni sinima àgbéléwò yìí!. N ò tiẹ̀ lè sọ púpọ̀. Ọ̀rọ̀ tán lẹ́nu. positive
Ó wúni lórí àwọn pẹ̀lú ọ̀nà tí àwọn osere gbà láti sọ nípa ìbásepọ̀ wọn pẹ̀lú ìbínú tí kò farahàn rárá. positive
Ó dùn móni gidigidi láti mọ bí orin Amazing Grace ṣe di kíkọ positive
Nípa ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó ga jù, sinimá yìí fi ọwọ́ tọ́ ọkàn mi gidi ni. À gbọdọ̀ wò ni. positive
Ìyanilẹ́nu! Eré ṣíṣe tó dára, gbígbé eré jáde náà rewà, ìtọ́sọ́nà tó wuyì. Eré yìí jẹ́ ìgbésí ayé. Mó jókò ó sí orí sónsó ìjòkó mi fún wákàti méje wíwo eré náà positive
Ó jẹ́ eré tí ó níse pẹ̀lú ǹkan tó o Kári ayé. positive
Ere tó dára púpọ̀ fún àwọn ọmọdé láti wò. Ere tó dára púpọ̀ fún àwọn ọmọdé láti wò ni Mirror Boy. Ere tó dùn tí a ṣe dáadáa tó sì kọ àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ ni ere yìí. Orin inú ere náà rẹwà ó sì dùn láti gbọ́. positive
Àti rí̀ Richard Mofe-Damijo (RMD) tó kó ipa Ejiro, ọmọ ìta tó ti fèyìntì fún ọ̀gá ọ̀daràn yàtọ̀ sí ipa tó máa ń kó tẹ́lẹ̀ bíi bàbá olówó. Ó sì ṣe dáadáa. positive
Ní ọjọ́ kini oṣù kẹjọ, ayẹyẹ Ijade mú ká rí ọpọlọpọ àwọn ènìyàn ju ẹyẹ àwọn ẹni ta n'reti lọ. Eré orí ìtàgé yìí jẹ eré tó sọ nípa àwọn ènìyàn tó ngbé ní àwọn ìlú tó lajú diẹ ṣe ngbiyanju láti lè bọ́ lọwọ ìgbé ayé wọn tí tẹlẹ àti gbé ayé wọn tẹlẹ ní ṣe pẹlu ọjọ ọla wọn. Níbi ayẹyẹ Ijade ile ìwé, baba dipo padà. Gbogbo àwọn ará mọlẹbi nìí oníkálukú òun o ṣe dá sí ìpàdé bọ rẹ. Sugbon àwọn tó tí rí tẹlẹ gbọdọ tí borí ìgbà tó fí kọ́kọ́ kúrò àti ìdí tí ọ fi tún padà wá ikẹdun wà tí sún kúrò. Àwọn òṣèré tó ya eré orí ìtàgé náà gbìyànjú àti pé ìtàn inú eré na kò tú sí ìta bikòṣe nipa ará rẹ. Òun tó nwụni lórí ní positive
O jọnilójú Ìpìlẹ tó dára tí a dá pọ pẹlú ìsíyèméati ìgbàgbọ asán, o ṣe sọ tẹlẹ dè òpin pẹlu ìpìlẹ̀ lílò tí o dáa. Mo nifẹ iṣẹ Kunle Afoláyan, ẹni tí o má n kópa nínú iṣẹ tí o n kọ, darí tí o sí má n gbé jáde. O le ṣẹ̀ ọpọlọpọ iṣẹ́,èyí tí o jọnilójú positive
Dokita Lanre jẹ ìyípadà tó dùn moní. Inu mi dun wipe mo wà lára àwọn ti o kọkọ wá nínú reluwe eré yii. Ìyípadà ti o dun mo ni ni o jẹ. Ìtàn na ni ìpìlẹ ti o dára tí wọn sì gbé jade dáadáa nipasẹ ìkópa awọn òṣèré ti o kún oju oṣuwọn. Eré tó yẹ fún wíwò. positive
Gẹ́gẹ́ Adenike, Gurira jẹ́ ohun àgbàyanu: Bákan náà ni ojú rẹ̀ ń dán yálà ó ń ṣe àfihàn ìdààmú tàayọ̀, ó sì mú àwọn ọ̀nà tí obìnrin yìí, tí ó jẹ́ arúgbó tí ń ṣe ojúṣe, tún fẹ́ darapọ̀ mọ́ ayé òde òní. positive
Èyí tó dára jùlọ positive
Eré tó dára. Eré tó tayọ, nínú àìní àfojúsùn fún ọjọ́ iwání orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pẹ̀lú gbogbo àìlera rẹ̀, ìrètí nínú ìsòtítọ́ àti ìsọ̀kan akín yorísí ìdàrúdàpọ̀. Ìkópa dídára òṣèré obìnrin ní àfikún sí afojusun lati mu ànfàní àsìkò ìpayà àti àìlágbára lọ. Eré tó dára pẹlú akoko ẹdọfu. positive
Eré tó dára fún àmì ẹ̀yẹ Eré tó dára fun àmì ẹ̀yẹ ati àwọn òsèré inúu rẹ̀ ṣe dáadáa àti eré tó se bẹbẹ. positive
Ìtàn ńlá nìyí. Sinimá tó yáyì gidi ni. Ó sọ nípa ìbàjẹ́ àwùjọ wá. Ó bani lọ́kàn jẹ́ ṣùgbọ́n òótọ́ ni. positive
Ó mú kí kíkọ́ síi nípa ìtàn Nàìjíríà wùmi. Èyíkéyìí eré tí ó bá mú mi láti kọ́ ẹ̀kọ́ síi á gba òṣùwọ̀n ìràwọ mérin nínú ìwé mìi. positive
Sinimá gidi tí ó ń kó àyà ẹni sókè ni Ní àkọ́kọ́, mò ń wò ó bóyá yóò dára àpé ìdàkejì rẹ̀ nítorí n kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa àwọn sinimá Nàìjíríà tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní òpin fíìmù yìí (eléyìí tí wọ́n rí ṣe dáadáa), mo wá gbà pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fojú kojú pẹ̀lú fánrán ohùn àti àwòrán tí kò ní ẹgbẹ́ ni. Mo le è fi ọwọ́ rẹ̀ sọ àyà pé kí àwọn ènìyàn wò ó. positive
Eré tó dára pẹlú idapọ asa ni ona tó dára. Ẹkọ pọ lati kọ latara obìnrin akínkanjú to gbìyànjú láti ipo re ninu Aye tó awọn ọkunrin joba le lori. Eré tó dára gidigidi. positive
O dara, e pa àtúnyẹwò òdì tí Ní tòótọ,o ya ni lẹ́nu , mi kò gbàgbọ́ wípé Nàìjíríà ni wón ti ṣe, iṣẹ́ - lọ́pọ̀ rẹ jẹ́ pàtàkì, àwọn òṣeré rẹẹ ṣé mú yangàn. Gbogbo wọn ṣa ipá wọn dáa dáa,o sí dùn. positive
Ìwádìí tímọ́tímọ́ tí ó gbé àwọn ìdojúkọ abiyamọ jáde. positive
Nǹkan tuntun Pẹ̀lúpẹ̀lú u a kò ṣe gba ti ere yìí, mo lérò pé gbogbo wàhálà Namaste yẹ ní wíwò kò tilẹ̀ ju iṣẹ̀kan lọ fún ṣíṣe nǹkan tuntun tó yàtọ̀. positive
Fíìmù to dara Mo feran itan na. Mo feran sise Eré ati wipe itan na ba awon nkan ti o n sele ni awujo wa. positive
“Farming” ń fa ìrora ní wíwò, ṣùgbọ́n Idris jẹ́ ìràwọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbórísókè. Beckinsale náà kàmìmì gẹ́gẹ́ ìyá àwọn Tilbury. positive
Eré àgbéléwò onígbàdún uǹ positive
Fún ere náà ní ẹ̀yẹ díẹ̀. Ó dá bíi pé Fíìmù náà ń wuni, ó sì ní àwọn ìwà ipá burúkú díẹ̀, ṣùgbọ́n mo ríi gẹ́gẹ́ ohun tí ó jẹ́ pàtàkì láti sọ ìtàn náà. positive
Fíìmù apanilẹ́rìn-ín Ere yìí kún fún ẹ̀rín. Mo kàn ń rẹ́rìn ni láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. positive
Èyí dára. Hmmm... Ere àgbéléwò gidi nìyí, kò bẹ́ẹ̀ lọ. positive
Won se fún iṣẹju merin din ni adọrin, ọmọ ifijiṣẹ (The Delivery Boy) je ojúlówó ìtumò wípé dídára lori ọpọ. Fíìmù yìí je ìkan lára àwọn fíìmù gidi ti o ti jade ni ọdọ Nollywood. Awọn to ṣe ní òye láti pa ìtàn ti o dára tí o sí pelu ìmọ - ẹrọ tó dára. A gbádùn rẹ nígbà tí a woni èní, bẹ sí ní akojọpọ eniyan ti a ko wo. Gbogbo wa la kuro ni iyara láì ni ìbànújẹ. O sí dá wa lóbẹ mi o ṣe rí fún eyin naa. Ọmọ ifijiṣẹ náà(The Delivery Boy)ko pẹ, ṣugbọn a lè sọ fún yín pẹlu ìgboyà wipe,tí e ní fíìmù tí o jẹ kẹ sanwo fún láti wò tí e sì lè tí lẹyìn,ọmọ ifijiṣẹ náà(The Delivery Boy) ni o yẹ kó jẹ. O ní ìgboyà o sí tún tẹ síwájú. positive
Eré àgbéléwò dára! positive
Ó yàtọ̀ gedegbe sí àtẹ̀yìnwá. Mo ti wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ Fíìmù tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Jíjẹ́ ògidì wọn máa ń yàtọ̀ nípa ipa ìtàn, àgbékalẹ̀ cinema náà, eré ṣíṣe, àti ohùn ṣe dára sí. Fíìmù yìí tayọ ju gbogbo àwọn yòókù ní gbogbo ọ̀nà. positive
Wiwa ti ọjọ ori dramedy ti o padanu ọna rẹ ni awọn ọna opopona ti Afirika ode oni. positive
Eré Nigeria Prince tayọ nínú ètò rẹ̀, èyí losi jẹ kí o jẹ àfikún sí àwọn eré ti o nííṣe pẹ̀lú ọ̀ràn positive
Kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ ó ń rẹwà bọ̀. Eré àgbéléwò yìí dá lórí ọ̀rẹ́ àti ìgbà èwe métó ja jà oríṣiríṣi ìdíwọ́ láti wà papọ̀ positive
Ìdarí eré àgbéléwò àkọ́kọ́ tó níyì Mo ṣàwárí rẹ̀ nínú eré àgbéléwò “Tubi”, mo gbádùn rẹ̀. Ó ní ibi tó fì sí ṣùgbọ́n eré àgbéléwò náà dára. Eré àgbéléwò tó dára ni. positive
Irọ́ mà ń jọ òtítọ́. Ṣé lòótọ́? positive
Lákòótán, ó dùn bi ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù Nollywood, kò ṣòro láti mọ̀; àwọn alátakò àti àwọn tí ò kin ṣe alátakò kò ṣòro dá mọ. positive
Eré àgbéléwò yìí nílò ìyìn tó ju eléyìí lọ torípé ó jẹ́ eré ṣìṣe tí akójọpọ̀ àwọn ìsẹ̀lẹ̀ rẹ̀ kún ojú òsùwọ̀n. Mi ò tíì rí eré àgbéléwò nípa àjàkálẹ̀ àrùn bayii ri, eléyìí jẹ́ titun. positive
Mo nifé eré àgbéléwò yìí , àmọ́ mi ò tilẹ̀ le sọpé bóyá eni bayi lókú tàeni bayìí ni ko kòkú. Eré èrùjèjè ni. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́pẹ́ ọmọ odún méje ni mí, eru o si ba mi. Mo máa fún ní méfà lórí òṣùnwọ̀n. positive
Eré tó mórí wú , tó sì mórí yá , àti pé o fi hàn gedengbe pe Ìtàn ìrírí ayé ni. positive
Ó fínjú. Eré ṣíṣe àti ìtàn eré nà dára, ṣùgbọ́n igbéjáde eré na kù díẹ̀ ká tó. Parí parí eré nà dára. positive
Eré àgbéléwò alágbára to ń fọwọ́ tọ́ni lọ́kàn. positive
Ko sọ́rọ̀ púpò lórí rẹ̀. Eré gidi tó dá lórí òṣèlú ìlú-ọba positive
Àwọn ìpele kọ̀ọ̀kan nínú eré àgbéléwò yìí tọ́ni lọ́ọ́kàn. Ìwọ náà wòó. positive
Ipá ohùn tó tayọ Eré àgbéléwò yìí dára. Àwọn òṣèré na jáfáfá. Ìparí eré na rúṣùgbọ́n ipa ohùn je èyí tó dára nínú oríṣiríṣi tí mo ti gbó nínú àwọn eré àgbéléwò ti Nàìjíríà dẹ̀ní. positive
Eré àgbéléwò to dára sùgbón o fun àwọn omo odún méjìdílógún sókè. Eré àgbéléwò to dára fáwọn ọmọ odún méjìdílógún sókè. Mo gbádùn eré na jálè. positive
Eré àgbéléwò aládùn tó sì ṣíni ló Eré àgbéléwò yii fi òrò ifiranse pàtàki si àwọn oun to ń lo nínú ìlú . Gbogbo ipele nínú eré lo dùn wò. positive
Ìgbésè ìgbóyà tó wúni lórí Dájúdájú mo gbádùn eré àgbéléwò yìí… pàápàá ju lọ èmi ti ń kin wo eré àgbéléwò ti Nàìjíríà ( tàka pè ní Nollywood?) positive
Ìyàlẹ́nu lónà àrà positive
Ìgbésè nla nínú ilé-isé ìgbé sinimá jáde Àwọn òsèré ti wọ́n lò dara , wọ́n sì kopà ìpín wọ́n dáradára . Wón gbìnyànju . O je àrídáto dára fun àwọn eré àgbéléwò ti Nàìjíríà. positive
Eré sinimá na mọ́n. Ó kún fún àwọn gbajúgbajà òṣèré, eré náà jágeree, o si tun tóka si àwọn ìsèlè to ń dàmú orílè-èdè Nàìjíríà positive
Ó yé àwọn adúláwọ̀ tó wà ní òkè òkun dáradára. Ó sọ nípa ìrírí ì mi gẹ́gẹ́ bíi adúláwọ̀ tí kò gbé nílẹ adúláwọ̀ tí ó sì ń gbìyànjú láti wá ibùgbé mìíràn.Fíìmù tó dára. positive
Gbogbo ìwà ìbàjẹ́ burú tó ni sinimá yìí fi hàn. positive
Ere yìí ìtàn tòótọ́ tí ó sì jẹ ìṣe ọpọlọ positive
Sibẹsibẹ, eyi kuna lati jẹ ohunkohun miiran ju alaidun. Kò mú ọgbọ́n wá rárá negative
Ìṣèṣe búburú púpọ̀, ṣùgbọ́n fíìmù náà tún j́ẹ ìdánilárayá. negative
Èyí kò dáa rárá. Ìṣekúṣe gbá à ni àwọn òṣèré náà ṣe. negative
O dun ó tilè jẹ́ pé àṣìṣe wà nínú rẹ. negative
fíìmù yí dàbí ǹkan lára asòpá pọ́ tì lábẹ́-ìdàgbàsókè ẹ̀rọ pẹ̀lú kan ìdàjì ọkàn láti fìfẹ́hàn sínú. negative
Ọmọ ilé ìwé ẹ̀kọ́ gíga gan-an ó ṣe àkóso fíìmù yìí. negative
Mo kórira sinimá yìí gan-an ni ò negative
Ìșọwọ́ ṣeré àwọn òșèré yẹn burú jáì, wón ṣe kọ eré náà tilè tún wáá burú bàjẹ́. negative
Òṣèré náà wà ní igi tí ó dára jùlọ, ọ̀rọ̀ sísọ náà fẹ́rẹ̀ sí orin nínú , bí ẹnipé àwọn òṣèré nígbàgbogbo ní ìtara pẹ̀lú àwọn láìní wọ̀n. negative
Gbogbo ohun tí ó wà nínú fíìmù yí ni ó sọ nípa isuna tí ó kéré negative
Gbẹ láti àsìkò negative
Ìsekúse gbàá negative
Àwàdà Nollywood gbòòrò nìkan ni ipò ṣe ni ò dání lójú nítòótọ́. negative
Charmed kò fa ni mọ́ra. Rárá negative
Ó burú Ìran náà dúró bẹ́ẹ̀ sì ni àti si ti ó dàpé kò lọ sí ibì kan . negative
Torí pé ó dá lé orin jẹ́ burú jáì negative
Ọ̀rọ̀ ìtàn . Ìtàn náà burú àtipé Ìtàn náà kò ṣe gbàgbọ́ negative
Mo rẹ́rìn dákú negative
bànújẹ́ ọgbẹ́, 'Levi' jẹ eré tí kò ní ìdí. negative
Fiimu naa jẹ iyalẹnu fun aini aanu ara ẹni, ṣugbọn o jẹ ki iriri “Ogbin” jẹ alaanu fun awọn olugbo paapaa. negative
Mo dá mi lójú pé yóò tí dára jùlọ bíi fíìmù kúkúrú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀wá sí ọgbọ̀n láti ṣe ìdánwò omi náà. negative
eré tí kò ní ìdí. negative
Ti ìpinnu dáradára ṣùgbọ́n ìgbìyànjú má gbowó láti gbé olùwò náà. negative
Ronú àti ṣe Indomie láìsí oun àdídùn. Eré yi kò da débi pé, óku díè kó parí nkò mọ oun ton sẹ̀lẹ̀. negative
Bíi àwàdà kẹríkẹrì ni wọ́n ṣe to eré yii. negative
"Wó̩n kàn s̩e àtòpò̩ ò̩kan-ò-jò̩kan ẹ̀fẹ̀, àwọn àwòrán apanilérìn-in tó ti wà lórí ìtàkùn abánidó̩rè̩é̩ lásán ni. Wọ́n tó gbogbo rẹ papọ̀ wọn sì pè é ní eré tiwọn. Tí ó bá jẹ́ ẹni tó wà lórí ìtàkùn abánidó̩rè̩é̩ ni, wà á ti ṣe àkíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ won bẹ́ẹ̀ni kò sì dájú pé wo̩n yóò pa ọ́ lé̩rìnín. Ìkùnà pátápátá ni ""Social Media 101"". Ìdójútì ńlá ni!" negative
eré yí kò dún negative
Eré Nigeria míràn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọdùn ṣùgbọ́n tó jẹ́ kòròfo. Nkò lè sọ pé kí ènìyán wòó negative
Kìí ṣe pé ó burú bẹ́ẹ̀ náà ṣùgbọ́n ìṣọwọ́ kọ eré àti ìdarí rẹ̀ ni kò ní àbójútó tí ó péye negative
Ìbẹ̀rẹ̀ fíìmù yí kàn dàìgbà tí ènìyàn kó ẹyẹlé pọ̀ mọ́ adìyẹ ni. Kò sí àlàyé nípa Laila kàn ṣe fara hàn. negative
Isọ itan ti ko dara pupọ… ati atunkọ itan-akọọlẹ pupọ nitori ìtàn fiimu naa negative
Ìdádúró. Ọ̀fẹ́. Àti àìmọ́gbọ́nwá. negative
Kìí ṣe eré gidi negative
bànújé̩ o̩kàn gbáà ni eré yìí. negative
óṣo nípa ìtàn kékeré kan èyàn lé búra pé ọmọ ilé èkọ́ alákó bèrè lósáré kọ́ fún eré ìbílè ọdún tókojá negative
Tí àkókò rẹ jẹ ó lógún,tẹ'pá mọ' ṣẹ́ kí o lè yẹra fún eléyìí. negative
jẹ́ fíìmù le jẹ́ búburú, ṣùgbọ́n pàtàkì? negative
Tí ó bá jẹ́ wípé mo jẹ́ aṣàkíyèsí fíìmù tí mo wá ọ̀nà láti má kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mí, mi olè roun fún ohùn kan tó dára nítòótọ́ oun tí a nílò fún àyẹ̀wò negative
Ó pẹ́ jù, Ìṣeré tó burú ,àìbáramu tó pọ̀ wà níbẹ̀ negative
ìtàn sísọ tipátipá àti eré orí ìtàgé tí óún dótini ní ìwà eni afìwàpamọ́ yí. negative
Báwo ni eré kan tó ní kókó ọ̀rọ̀ yìí ṣe máa ń tètè dà rú? negative
èyí jẹ́ ìtàn tí ó ní agbára fún ìyìn pàtàkì, ṣúgbọ̀n ìpànìyàn kò dára àti kí ó jẹ́ kí ó rọrùn gbàgbé. negative
eré yí ní ọpọlọ ju 'ojú kẹta'' lọ tí ó jé pé ara eré àtijó pẹ̀lú 'Pa OluJacobs. yà gò fùn èyí negative
Àwọn òṣèré ìtàgé túbọ̀ maa n dótini negative
SURVIVAL OF JELILI jẹ́ àfihàn aláyẹ̀yẹ rúdurùdu àti ohun tí kò yẹ kí ojú máa rí. negative
Ni ìpárí fíìmù Chief Daddy àkọ́kọ́, ṣíṣe àfihàn òșèré tuntun ni abala tí ó gbẹ̀yìn tọ́ka sí apá kejì ṣùgbọ́n Chief Daddy apá kejì tún wà fi ègún àwọn sinimá apá kejì lọ́nà tó tún bụrụ jáì. negative
Kò yẹ kí ó tán síbẹ̀ yẹn. Àwọn tí ó kọ́ ọ́ ò kún ojú òsùnwọ̀n. negative
dìtẹ̀ náà kò jẹ́ òtítọ́ pátápátá àti pé ó wà ní gbogbo ibi. negative
ìfowò àti àkókò ṣòfò negative
Eré yìí kò dùn rárá, kódà kò ní wu ọmọdé. negative
òsì paraku . Ọ̀nà ìkọtàn yí burú . Mi ò lè mú ra mi láti wò ó dé ìparí . negative
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọn kìí tẹpá mọ kíkọ ìtàn ère sinimá. Sinimá yìí kàn rí bákan ṣá. negative
bóbá sejẹ́, tí obá mọ̀ ẹnìkankan rí óye kí ó jẹ ìyà, rà tíkẹ́ẹ̀tì negative
Ọ̀kan tí ó burú, pẹ̀lú ariwo yìí, mo lérò pé eréoníṣe tó tayọ nì í ṣùgbọ́n eléèyí jẹ́ ọ̀kan nínú èré tó burú jáì tí mo ti rí nígbà díẹ̀ negative
Mo tilẹ̀ ń wa ilẹ̀ láàkọ́kọ́ Ere náà ni àkókò ṣùgbọ́n Oni ìṣòro ìfàyèsí ,o nilo í ṣàtúnṣe , àti pé otun gun negative
Ṣé ẹlòmíràn gbà pẹ̀lú mi wípé ohun tí wọn fi síwákàn dààgbélébùú láàrín Àǹtónì Mákì àti Dáníẹ́lì Kàlúyà ni? negative
Fíìmù òmùgọ̀ negative
Thecall' jẹ́ oun tí kò dàgbà negative
Ohun gbogbo dàbí ẹnipé kò ní ibi-afẹ́dé, kékeré, bí ẹnipé ìtàn náà (èyítí ó jẹ́ ni àwọn àkókò tí kò ní ìdáríjì) kò ṣe ìṣeré bí ó ṣe ṣe jáde nìkan tí ó yára kọja. negative
"Eré yìí kò dára rárá fún ẹnikẹ́ni títí kan àwọn ọmọdé. Eré tó ń run ènìyàn ninu ni eré ""Another Father's Day"". Eré tó lè ru ìbínú sókè nínú ènìyàn ni eré yìí. Ò̩nà eré sís̩e yii kò gbé iṣé̩ o̩po̩lo̩ jáde rárá. Eré tó lè mú kí ènìyàn má nífẹ̀é̩ sí Nollywood ni eré yìí jé̩. Ìfowó àtàkókò àti agbára ṣòfò ni. Àtúbọ̀tán ère o̩ló̩mo̩kúùyà nìyí. A rọ̩ àwọ̩n olólùfẹ́ ère àgbéléwò láti má fi àkókò wọn ṣòfò lórí irú ère yìí." negative
Mọ́kàndílọ́gbọ̀n nínú ọgọrun negative
pàdánù ànfàní negative
Wákàtí méjì ṣòfò Kìí ṣe oun ti mo retí, eré nàà kún fún ẹ̀fẹ̀ tó n bíní nínú. negative
Ìtàn yẹn kò ṣe ohun kankan lára tèmi jàre. Nígbà tí ó yá, mo lè sọ ohun tí yóò tẹ̀lé ohun tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́. Wọ́n tilẹ̀ tún wà ń ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí wón ṣe tẹ́lẹ̀ nígbà tí yóò fi di ìgbẹ̀yìn eré yìí. negative
Ìf'àkókò ṣòfò Eré náà kò yéni tó, kò m'ọ́pọlọ dáni, ò kún fún ọmọ Nàìjíríà tón se àsìlo ọ̀rọ̀ Jàmáíkà. negative
Kìí ṣe ti lílo oun apanilérìn, iṣẹ́ àti ìjà ṣùgbón pẹ̀lú bí kò ṣe dáa tó a máa ṣeni ní kàyéfì. negative
Eré onífẹ̀ẹ́ apani lẹ́rìn-ín níbi tí ilé ìdáná, ilé ìtura àti orílẹ̀-èdè tí à ń rí níbí kò ti jọ ara wọn. negative
Èmi yóò fẹ́ láti jẹ́ ... apániláyà Àwàdà tí a wò ní ìgbà pípẹ́ negative
Kò kọjá. Ó jẹ́ ìdánilárayá. Kò yanilẹ́nu. negative
Mi ò fọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà. Ìtàn tó dára gidigidi ni ṣugbọn àwọn ẹ̀bùn tí ò sọ kò kún tó. negative
Mo fẹ́ràn fíìmù yìí Ṣùgbọ́n mi ò kàn le sé náàni. Gbígbé lọ́ra ṣùgbọ́n tún jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. Ó mà burú gan ò. negative
Ní gbogbo ọ̀nà ni sinimá yìí kò fi dáa rárá. Ó s’eni láàánú pé ó dín díẹ̀ nínu wákàti méjì àkókò ayé mi ni mo fi ṣòfò lórí eré yìí. negative
Midnight Crew' jẹ́ eré kan tí kò dùn tí ènìyàn ni láti yẹra fún ní sinimá. negative
Agbara miiran ti o dara ti bajẹ nipasẹ kikọ buburu. negative
Pàpá Ajasco wá sí sinimá ní ìyàlẹ́nu ìyàlẹ́nu àti àwàdà aṣiwèrè aṣiwèrè yìí. negative
Mo fẹ́ láti fẹ́ràn fíìmù yìí gaan. Mo ní ìfẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré àti dídára ìṣelọ́pọ̀.Ó dára, ṣùgbọ́n bótilẹ̀jẹ́pé ó jẹ́ wákàtí kan nìkan etí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú mẹ́rin, ó dàbí pé ó fá lórí láíláí. Mo ní láti dúró àti bẹ̀rẹ̀ fíìmù yìí. Mo ti párí níkẹhìn lẹ́hìn osù díẹ̀. negative
Ó dùn mí pé mo fi àkókò ṣòfò lórí eré yìí negative
Ìbànújẹ́ pé ohùn orin púpọ̀ ló wà jákèjádò fíìmù náà àti pé ó ní ipa tí ṣíṣe fíìmù náà ní ìmọ́lára ẹni ọgbọ̀n ọdún. negative
Máse gbọ́kànle díwọ̀n Ìgbéohùn kan jáde negative
ìdọ̀tí pípẹ́ negative
Sinimá yìí burú débi wípé, kò sí àsopọ̀ láàrin ìbẹ̀rẹ̀ àti àwọn apá tó kù. Èyí kò bójúmu ṣùgbọ́n sinimá yìí lè dára jù báyìí lọ. negative
Eré tí kò dára negative
Ó dára títí di òpin Àṣìṣe ńlá! negative
Mo nírètí jù báyìí lọ negative
gélé tí wákàtí méjì kọjá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ' ìpè láti òdò olórun' kòdùn negative
Èbùn ṣ'òfò Mo kúrò ní ilé ìwòran pẹ̀lú ìjákulẹ̀ negative
Èyí ni fíìmù tí ó bá jẹ jù tí mo ti wò rí negative
Ọ̀rọ̀ tí kò l'agbára, àfihàn ìjà tí kò múná d'óko negative
Fíìmù Fine wine 🍷 kò bá dùn ju báyìí lọ àmọ́ wọn kò rí ìtàn tí ó dára tó yẹn túmọ̀ dáadáa àti pé ohun tí ó tún báà jẹ́ ni bí wọ́n ṣe ń yọ́ bíi ìgbín. negative
Mi ò le fọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà negative
Àsọdùn nípa eré tí kò dùn Àkójọpọ̀ òṣèré lè bí elòmíràn nínú negative
bóse jpé Zebé Ejiro lóṣé tí Chico Ejiro ló darí rẹ̀, àgbà òsèré méjì, ọkọ̀ alá lọ́sí èkó' kò délé láyọ̀. nígbà àtijọ́. ìfiwósòfò negative
N kò le sọ fún ẹnikẹ́ni kí ó wo sinimá yìí. Wọ́n kàn lọ dá ohun tí àwọn kan ti ṣe tẹ́lẹ̀ ṣe ni. negative
Sinimá tí kò dára rárá ni negative
Titun. Ìgboyà. àìmọ́gbọ́nwá. Àìtẹ́lọ́rún. negative
"È̩hun olópòó kan ni, ó dára bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀. ""Lionheart"" jé̩ eré tó fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye ni ilé-is̩é̩ Nollywood. Wó irú atile̩yin ilè̩ òkèèrè tó rí gbà ló̩wó̩ Netflix, inú èmi pàápàá dùn láti rí èrè yìí ṣe lọ. Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ ni ère yìí tí sàfihàn pé tíwantiwa ni, kò sì pé̩ rárá tí a fi rí ìsò̩rò̩ǹgbèsì lédè Yorùbá. Ṣùgbọ́n ère náà fihàn pe olópòó kan ni ó ṣe n tẹ̀ síwájú. È̩hun rẹ̀ kò ní ipa kankan, ketekete ni ènìyàn lè sọ nǹkan tó kàn nínú eré náà. Ìyàlẹ́nu ni èyí jẹ́. bẹ̀síbẹ̀, mo sì gbóríyìn fún ìgbèjàde ère náà nítorí pé ó gbámús̩é àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀dá ìtàn ni wọ́n kó ipa wọn ó ṣe tọ́ àti ó ṣe yẹ̩ àyàfi Peter Okoye tó wá kule. Fún tí ìdarí, àfi kí ènìyàn gbóríyìn fún ìgboyà Genevieve fun ìṣe takuntakun to ṣe. Lákòótán, kò sí ìdánilópé wà á gbádùn ẹ̀fẹ̀ yìí ó ṣe lérò" negative
Èmi gbà fún sinimá tí ó bá jẹ́ pé àwọn òșèré àti àwọn ibi tí wọ́n lò jẹ́ ti òkè òkun. negative
Fíìmù ti o ni àwọn gbajúmò Òṣeré nínú sugbọn ṣíṣe rẹ kò dára rárá negative
Kò fọwọ́sí. Dejavu jẹ àpẹẹrẹ eré Yorùbá negative
Kò fọwọ́sí fun sinimá. Eré yìí ni wàhálà púpọ̀. negative