raw_text
stringlengths 2
128k
|
---|
igbó òkè orashi igbó òkè urashi jẹ́ igbó kan lábẹ́ àbò ìjọba ní ìpínlẹ̀ rivers ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà níbi òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò urashi ní abúlé ikodi ti ahoada west igbó náà gba ilẹ̀ tí ó tó 25165 ha 97163 sq mi àjọ ramsar convention ká mọ́ àwọn igbó tí ó ti ó ṣe pàtàkì ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2008 ìgbà ní ibè ìgbà igbó òkè urashi ní ìgbà òjò àti ìgbà ẹ̀rùn ìgbà òjò ma ń wá láti oṣù kẹta títí di oṣù kọkànlá ìgbà ẹ̀rùn sì ma ń wá láti oṣù kejìlá sí oṣù kejì omi láti odò urashi ma ń ya wo igbó náà láti oṣù kẹsàn-án sí oṣù kọkànlá |
cross river national park cross river national park jẹ́ pápá ìṣeré kan ní ìpínlẹ̀ cross river nàìjíríà ó pín sí apá méjì apá okwangwo tí wọ́n dá kalẹ̀ ní ọdún 1991 àti apá oban tí wọ́n dá kalẹ̀ ní ọdún 1988 ilẹ̀ rẹ̀ tó 4000 km2 púpọ̀ nínú rẹ̀ sì kún fún igbó pàápàá jùlọ ní àríwá àárín pápá ìṣeré náà àti apá pápá ìṣeré náà tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò apá kan pápá ìṣeré náà wà lábẹ́ ìdarí ìjọba congo bákan náà pápá yìí jẹ́ ilé fún oríṣríṣi ẹranko àwọn ẹranko bi common chimpanzees drills àti cross river gorillas |
kainji national park kainji national park jẹ́ pápá ìṣeré ní ìpínlẹ̀ niger àti kwara orílẹ̀ èdè nàìjíríà wọ́n da kalẹ̀ ní ọdún 1978 ó gba ilẹ̀ tí ó tó ó pín sí apá mẹ́ta apá ti adágún kainji níbi tí wọn ò ti gba iṣẹ́ apẹja láyè igbó borgu tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn adágún náà àti igbó zugurma nítorí àìsí àbò tó péye ni àgbègbè náà àwọn àjọ pápá ìṣeré ní nàìjíríà dáwọ isẹ́ àti ìwádìí dúró ní pápá ìṣeré kainji national park ní ọdún 2021 wọ́n tún dáwọ isẹ́ dúró ní chad basin national park àti ní kamuku national park |
ààlọ́ erinmi ìjàpá àti erin òkè apààlọ́ ààlọ́ o agbe ààlọ ààlọ̀ apààlọ́ ààlọ mi dá lórí ìjàpá tó dá'jà ṣílẹ̀ láárín erin òkè àti erinmi nígbà láíláí erin òkè àti ìjàpá jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ìjàpá jẹ́ àgbè nígbà tí erin òkè jẹ́ ògbójú ọdẹ apẹran ìjàpá àti erin a máa ṣe pàṣípààrọ oúnjẹ oko bíi iṣu ikàn ẹ̀gẹ́ ṣùgbọ́n kò tẹ́ ìjàpá lọ́run bíi kí erin òkè máa fún ní eran lọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rẹ́ àti àgbà ijàpá ní lọ́kàn láti fi ìyà jẹ erin òkè ìjàpá jẹ́ jomijòkè ẹranko tó le gbé nílè àti nínú omi bíi ìjàpá ṣe ń gba ẹran lọ́wọ́ erin òkè bẹ́ẹ̀ lo ń gba eja lọ́wọ́ erinmi ní ọjọ́ kan ìjàpá lo bá erin òkè pé kí ó bá òun wá ẹran ńlá ki òun fi se àsè fún àwọn ẹgbẹ́ òun lèyí tí òun ṣe tán láti fi ẹja nla pààrò fun inú erin òkè dùn láti bá ìjàpá wá ẹran ńlá fi pààrò fún ẹja kí òun lè jẹ nkan mìíràn yàtọ̀ sí ẹran gbogbo ìgbà láì mọ̀ pé ìjàpá fẹ́ fi ìyà jẹ òun ni bákannáà ìjàpá tún lo bá erinmi pé kí ó fún òun ní ẹja ńlá kí òun fi ẹran ńlá pààrò fun erinmi fun ìjàpá ni ẹja bẹ́ẹ̀ ni erin òkè fun ìjàpá ni ẹran ó sì dá ọjọ́ méje fún àwọn méjèèjì ìjàpá tòun taya àti àwọn ọmọ rẹ̀ ńṣe bẹ́ẹ̀ni wọ́n sọ kí ọjọ́ méje tó pe ó twa i okùn àgbà to yii o gbé lọ fún erin òkè pe okùn náà ni yóò fi wọ́ ẹja ninu bẹ́ẹ̀ ó sọ fún erinmi pé òun ti wá okùn tí yóò fi wọ́ ẹran láti òkè sinu omi nigbati ọjọ́ méje pe ìjàpá mú erin òkè lọ sí etí odò lati fa eja jáde nínú ibu bákan náà ó wọ inú omi lọ láti sọ okùn mó erinmi lọ́rùn lát wọ́ ẹran sínú omi bi ìjàpá ṣe kúrò ni ọdọ erinmi tí ó rìn sókè díẹ̀ lo ti sọ fún àwọn méjèèjì pé ó yá o bẹ́ẹ̀ ni erinmi n fa eran láti òkè tí erin òkè sì ń ẹja láti inú ibú gbogbo igi ń wo lókè bi erin òkè ṣe ń jà fitafita láti fa eja bẹ́ẹ̀ ni odò n daru bí erinmi náà se ń jà láti fa ẹran sínú omi àwọn méjèèjì gbìyànjú títí di ọ̀sán kí erinmi tó so pé òun yóò gòkè lo wo ẹran naa báyìí ni o gán-án ní ọ̀rẹ́ re erin òkè wọ́n kí ara wọn pé ìjàpá ló dá a ṣílẹ̀ inú bí erin òkè ṣùgbọ́n ìjàpá ti sa sábẹ́ ìràwé erinmi padà sínú omi bẹ́ẹ̀ni erin òkè padà sílé tí ó sì pinnu pé oun kò ṣíṣe ọdẹ mọ bẹ́ẹ̀ ni ko jẹ eran mọ ìṣe ọdẹ pípa ẹran ló fìyà jẹ òun lọ́wọ́ ìjàpá láti ìgbà náà ni erin ti ń jẹ koríko ẹ̀kọ́ ààlọ àlọ́ yí kọ́ wa pé kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú gbogbo ohun tí a bá ti ní |
hilda baci hilda effiong bassey tí ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn mọ̀ sí hilda baci a bi ní ọjọ́ ogún oṣù kẹ́sàn-án ọdun 1996 jẹ́ aláṣè àti òṣèrébìnrin ọmọ orilẹ-èdè nàìjíríà ní osù kẹ́jọ ọdún 2021 o jáwé olúborí nínú idije jollof faceoff” ìpìlẹ̀ àti iṣẹ́ rẹ̀ hilda wá láti ìjọba ìbílẹ̀ nsit ubium ìpínlẹ̀ akwa ibom nàìjíríà wọ́n bi ní ọjọ́ ogún oṣù kẹsàn-án ọdún 1996 ó kàwé gboyẹ̀ pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ nínú ìmò sociology ní yunifásítì madonna okija òun ni olóòtú ètò dine on a budget ní orí ìkànnì pop central tv dstv channel 189 iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré èyí ni àtòjọ awọn fíìmù tí o tí kópa ìgbìyanjú rẹ̀ láti kọjá gbèdéke guiness record ní oṣù kẹta 2023 hilda fí léde pé òun yó gbìyànjú láti wákàtí tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìtàn ọmọ ènìyàn ẹni tí ó dáná fún wákàtí tí ó pọ̀ jùlọ tẹ́lẹ̀ ni lata tondon ó dáná fún wákàtí ẹ̀ta dín ní àádọ́rùn àti àrún dín ní àádọ́ta ìṣẹ́jú 87 hours 45 minutes ní ọdún 2019 ní ọjọ́ kọkànlá oṣù karùn-ún ọdún 2023 ó bẹ̀rẹ̀ iná dídá náà ó sì pe àpèlé rẹ̀ ní cook-a-thon ó kọjá gbèdéke tí lata tondon gbé kalẹ̀ ní ọjọ́ kẹ̀ẹ́dógún oṣù karùn-ún ọdún 2023 ní dédé ago mẹ́jọ ku ìsẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún àárọ̀ ọjọ́ náà hilda fi ìsẹ́jú márùn-ún kọjá gbèdéke lata hilta ni lọ́kàn láti dáná fún wákàtí mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún96hrs àwọn òtòkùlú ènìyàn ní nàìjíríà ni ó ti kàn sí hilda láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iná dídá àwọn bi gómìnà ìpínlẹ̀ èkó babajide sanwo-olu olùṣọ́ àgùntàn àgbà ti ìjọ harvester international bolaji idowu àti olórin tiwa savage ígbákejì ààrẹ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ọ̀jọ̀gbọ́n yemi osinbajo tún pèé lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láti gbá níyànjú nígbà tí ó ń dáná lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ nàìjíríà ni ó ti ya wo ọgbà ilé tí ó ń ti dáná láti fi àtìlẹ́yìn wọn hàn àwọn míràn sì ń kéde rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára |
diesel locomotive factory marhowrah the diesel locomotive factory marhowrah jẹ́ àpapọ̀ ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú-irin ti ge ti orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà pẹ̀lú àwọn reluwé ti orílẹ̀-èdè india fún ṣíṣe ọkọ̀ ojú irin tí ìwọ̀n agbára gíga rẹ̀ tó 1000 tí wọ́n rọ fún bíi ọdún mẹ́wàá síwájú si láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn òpópónà ojú-irin orílẹ̀-èdè india ilé iṣẹ́ yìí wà ní marhaura tí wọ́n sì tún máa ń kọ ọ́ báyìí marhowrah tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ọkọ̀ náà ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2018 ilé iṣẹ́ náà sì tún ṣe ibi ìtúnkọ̀ ṣe méjì ni ìlú gandhidham ní gujarat àti roza ní uttar pradesh |
igbó òkè cameroon igbó òkè cameroon jẹ́ àwọn igbó tí ó wà ní àwọn òkè gulf of guinea tí ó sì pàlà láàrin orílẹ̀-èdè cameroon àti nàìjíríà agbègbè ibè kún fún àwọn igi àti koríko àwọn igi ibè ń díkù si àwọn koríko rẹ̀ ń sì pò si nítorí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ |
igbó òkè cameroonian |
kamuku national park kamuku national park jẹ́ ọ̀kan lára àwọn pápá ìṣeré nàìjíríà tí ó wà ní ìpínlẹ̀ kàdúná nàìjíríà pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó tó a 1120 km2 nítorí àìsí àbò tí kò péye ní agbègbè náà àjọ pápá ìṣeré fún orílẹ̀ èdè nàìjíríà dáwọ́ iṣẹ́ dúró ní pápá ìṣeré náà àti ní pápá ìṣeré kainji national park àti chad basin national park ìtàn àti ibi tí ó wà pápá ìṣeré náà wà ní ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ kaduna ó sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kwiambana game reserve àjọ native authority forest reserve of birnin gwari ni ó da kalẹ̀ ní oin 1936 lábé ìjọba àríwá orílẹ̀ èdè nàìjíríà |
okomu national park okomu national park tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí okomu wildlife sanctuary jẹ́ igbó kan tí ó wà ní inú okomu forest reserve ní ìjọba ìbílẹ̀ ovia south-west ti ìpínlẹ̀ ẹdó orílẹ̀ èdè nàìjíríà pápá ìṣeré náà wà fi kìlómítà ọgọ́ta jìnà sí benin city igbó tí ó wà ní ẹgbẹ́ pápá ìṣeré náà jẹ́ ilé fún àwọn oríṣiríṣi àwọn ẹranko pẹ̀lú pẹ̀lú àwọn tí irú wọn ti fẹ́ parun ní ilẹ̀ àgbáyé igbó náà ń dínkù si nítorí abúlé tí ó wà níbẹ̀ ó sì jẹ́ ìdásí mẹ́ta títóbi rẹ̀ tẹ́lẹ̀ àwọn ilé isé kọ̀kan tún ń gegi nínú igbó náà |
old oyo national park egan orile-ede oyo atijọ jẹ ọkan ninu awọn ọgba-itura orilẹ-ede naijiria ti o wa ni iha ariwa ipinle oyo ati gusu ipinle kwara nigeria o duro si ibikan jẹ 2512 km2 ti ilẹ ni ariwa ipinle oyo guusu iwọ-oorun nigeria ni latitude 8° 15' ati 9° 00'n ati longitude 3° 35' ati 4° 42' e ipo naa ti gbe ọgba-itura naa si ibi ti ko ṣeeṣe ipo vantage ti agbegbe lọpọlọpọ bi daradara bi oniruuru eda abemi egan ati awọn eto aṣa/itan awọn agbegbe ijọba ibilẹ mọkanla ninu eyiti mẹwa ṣubu laarin ipinlẹ ọyọ ati ọkan ni ipinlẹ kwara yika rẹ ile-iṣẹ alakoso iṣakoso wa ni oyo agbegbe isokun ni opopona ọyọ-iseyin nibiti o ti le ṣe alaye pataki ati ifiṣura ilẹ-ilẹ ati aaye ti a ṣeto laarin agbala nla ti jẹ ki ohun elo naa nifẹ si gbogbo eniyan o jẹ ọlọrọ ni awọn ohun elo ọgbin ati ẹranko pẹlu buffaloes bushbuck ati ọpọlọpọ awọn ẹiyẹ o duro si ibikan jẹ irọrun wiwọle lati guusu iwọ-oorun ati ariwa iwọ-oorun naijiria awọn ilu ati awọn ilu ti o sunmọ julọ ti o sunmọ egan oyo atijọ ni saki iseyin igboho sepeteri tede kishi ati igbeti ti o ni awọn aaye iṣowo ati aṣa tiwọn fun irin-ajo itan ogba naa gba oruko re lati oyo-lle old oyo olu ilu oselu oyo nijoba awon yoruba o si ni ahoro ilu yii ninu ogba ile-itura ti orilẹ-ede ti bẹrẹ ni awọn ifiṣura igbo ijọba abinibi meji ti iṣaaju oke ogun ti iṣeto ni 1936 ati oyo-lle ti iṣeto ni 1941 awọn wọnyi ni iyipada si awọn ẹtọ ere ni 1952 lẹhinna ni idapo ati igbega si ipo ọgba-itura orilẹ-ede lọwọlọwọ ni ọdun 2022 ijabọ ṣe akiyesi pe laibikita awọn irin-ajo irin-ajo deede ati awọn ofin aabo ọgba-itura naa wa labẹ ewu nitori ọdẹ ati gedu ni afikun si ifipa agbo ẹran botilẹjẹpe iṣọtẹ ti dinku lati ibẹrẹ awọn ọdun 2000 ṣiṣe agbo ẹran jẹ iṣoro pẹlu awọn ẹgbẹ miyetti allah ti o gba pe ṣiṣe ẹran-ara ti ko tọ si jẹ ọrọ pataki ti o dojukọ ọgba-itura naa ṣugbọn sọ pe ọpọlọpọ awọn darandaran agbegbe ko mọ ipo gangan ti ọgba-itura naa tabi pataki ilolupo rẹ ní àfikún sí i onímọ̀ àyíká eme okang ṣàlàyé pé ìyípadà ojú ọjọ́ tún ti ta àwọn darandaran síhà gúúsù àti sínú ọgbà ìtura náà ni ọdun to nbọ awọn imuni ọpọlọpọ ti awọn awakusa arufin ati awọn darandaran ni afikun si awọn ọdẹ ṣẹlẹ lakoko awọn awakọ aabo ipo egan naa ni apapọ ilẹ ti o jẹ 2512km2 ati pe o wa ni apa gusu iwọ-oorun ti nigeria pataki ni ariwa oyo state ni latitude 8 o 15' ati 9 o 00'n ati longitude 3 o 35' ati 4 o 42' e ipo naa laiseaniani ti gbe egan naa si ipo vantage ti agbegbe ilẹ lọpọlọpọ bi daradara bi oniruuru ẹranko igbẹ aṣa ati awọn eto itan awọn agbegbe ijọba ibilẹ mọkanla 11 ninu eyiti mẹwa 10 ṣubu laarin ipinlẹ ọyọ ati ọkan 1 ni ipinlẹ kwara yika ile-iṣẹ alakoso iṣakoso wa ni oyo agbegbe isokun ni opopona ọyọ-iseyin nibiti o ti le ṣe alaye pataki ati gbigba silẹ ilẹ-ilẹ ati aaye ti a ṣeto laarin agbala nla ti jẹ ki ohun elo naa nifẹ si gbogbo eniyan ayika ogba naa bo 2512 km2 pupọ julọ ti awọn pẹtẹlẹ pẹtẹlẹ ni giga ti 330 m ati 508 m loke ipele okun odo owu owe ati ogun ni apa gusu lo nigba ti apa ariwa ni odo tessi yo awọn jade ti giranaiti jẹ aṣoju ti agbegbe ila-oorun ariwa ti o duro si ibikan pẹlu ni oyo-lle pẹlu awọn ihò ati awọn ibi aabo apata ni ariwa nla aarin aarin ti o duro si ibikan ni awọn oke-nla ti tuka awọn oke ati awọn agbejade apata ti o dara fun gigun oke omi ikere gorge dam ti o wa ni odo ogun pese awọn ohun elo ere idaraya fun awọn afe-ajo ododo ati bofun ogba naa ni awọn olugbe ti ẹfọn afirika kob bushbuck roan antelope hartebeest iwọ-oorun ọbọ patas ati waterbuck egan orile-ede oyo atijọ ti jẹ ibugbe tẹlẹ fun aja igbẹ ti iwo-oorun afirika ti o wa ninu ewu lycaon pictus manguensis sibẹsibẹ awọn eya ti a ti extirpated lati o duro si ibikan nitori lati ode titẹ ati awọn jù eda eniyan olugbe ni ekun |
agodi gardens agodi gardens èdè yoruba ọgbà agodi jẹ́ ọgbà kan tí ó wà ní ìlú ìbàdàn orílẹ̀ èdè nàìjíríà àwọn ènìyàn tún mọ̀ ọ́ sí agodi botanical gardens agodi gardens ibadan ọgbà náà gba ilẹ̀ tí ó tó 150 acres ìtàn orúkọ ọgbà náà tẹ́lẹ̀ ni agodi zoological and botanical gardens wọ́n dá agodi gardens kalẹ̀ ní ọdún 1967 ìkún omi ogunpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1980 ba ọgbà náà jẹ́ ó sì gbé ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko ọgbà náà lọ ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ sì tún ọgbà náà ṣe ní ọdún 2012 wọ́n sì tun sí ní ọgbà agodi ní ọdún 2014 |
àwọn òkè mandara mandara mountains aèdè yoruba àwọn òkè mandara jẹ́ àwọn òkè tí ó wà ní àríwá àlà láàrin cameroon àti nàìjíríà tí ó gùn láti odò benue ní dé àríwá ìwọ̀ oòrùn maroua ní àríwá òkè tí ó ga jù níbẹ̀ ni mount oupay àdúgbò náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùgbé pàápàá jùlọ àwọn tí ó ń sọ èdè chadi pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà mofu àti kirdi àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ibè àwọn òkè mandara jẹ́ ibi tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùgbé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ ibẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún òkè àti ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ òkè náà jẹ́ ibi àbò fún àwọn tí ó ń sá fún àwọn akónilẹ́rú àti ogun àwọn ènìyàn ibẹ̀ ti wá ọ̀nà láti gbìn ọ̀gbìn bí ó tilẹ̀ pé ilẹ̀ òkè ni ibẹ̀ |
millennium park abuja the millennium park jẹ́ pápá ìṣeré tí ó tóbi jù ní ìlú abuja olú ìlú orilẹ-èdè nàìjíríà ó wà ní agbègbè maitama nínú ìlú náà ọbabìnrin elizabeth kejì ni ó ṣe àfilọ́lẹ̀ pápá ìṣeré náà ní ọjọ́ kẹrin oṣù kejìlá ọdún 2003 ó sún mọ́ ilé ààrẹ orílẹ̀ èdè nàìjíríà odò kan la pápá yìí kọjá ó sì pín sí méjì apá kan pápá náà kún fún koríko àti igbó ó sì tún jẹ́ ilé fún àwọn ẹyẹ àti labalábá apá kejì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pápá náà ó sì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun àrà fún àwọn àlejò ayàwòrán ilé ọmọ orílẹ̀ èdè italy manfredi nicoletti ni ó ya àwọn ǹkan tí ó wà ní pápá yìí kí ó tó di pé wọ́n kọ pápá náà sì ti di ibi tí ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn ènìyàn láti abuja fẹ́ràn láti ma wá ara àwọn òtòkùlú tí ó wà níbi ifilọ́lẹ̀ pápá náà ni olusegun obasanjo mínísítà àgbà orílẹ̀ èdè united kingdom tony blair àti ọbabìnrin elizabeth kejì |
isaac boro park isaac boro park jẹ́ pápá ìṣeré kan tí ó wà ní agbègbè old gra ní olú-ìlú ìpínlẹ̀ rivers port harcourt wọ́n so pápá ìṣeré náà lórúkọ tẹ́lé isaac boro ẹni tí ó jẹ́ ajàfẹ́tọ́ ọmọ ènìyàn ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ibi tí ó wà ní pàtó ni 4°47'16n 4787960 7°0'19e 7005517 ó wà ní odi kejì mile one ó sì jẹ́ ilé fún erẹ́ baseball àti softball ní port harcourt ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti ọdún 2006 sí ọdún 2013 wọn ṣe ayẹyẹ international trade fair ọdọọdún níbẹ̀ ó sì tún jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ ìrántí ikú àwọn ọmọ ológun tí ó sọ èmí wọn nù lójú ogun fún ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti ayẹyẹ ìparí àwọn kópà national youth service |
the ap 42 compilation of air pollutants emission factors the ap 42 compilation of air pollutant emission factorsàtòpọ̀ àwọn ohun ìṣokùnfà ìtúsóde afẹ́fẹ́ ìdọ̀tí náà jẹ́ àwọn àjọ tó ń dáàbò àti mójútó àgbègbè ti orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà epa ìròyìn ohun ìtúsóde lórí ìdọ̀tí afẹ́fẹ́ àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ní ọdún 1968 ítí di 2018 update apá tó kẹ́yìn ni apá karùn-ún láti ọdún 2010 ìtàn ap 42 àtòpọ̀ àwọn ohun ìṣokùnfà ìtúsóde afẹ́fẹ́ ìdọ̀tí náà the ap 42 compilation of air pollutant emission factors jẹ́ àtòpọ̀ àwọn ohun ìṣokùnfà ìtúsóde àwọn afẹ́fẹ́ ìdọ̀tí ní iye àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣàfihàn iye ìdọ̀tí tí wọ́n tú sáfẹ́fẹ́ pẹ̀lú ìṣe nǹkan kan ní pàtó àtòpọ̀ yìí ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe tí àwọn elétò ìlera ti orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà sì tẹ̀jáde ní ọdún 1968 ní ọdún 1972 wọ́n dáa padà wọ́n sì tun gbé jáde gẹ́gẹ́ bí apá kejì látọwọ́ àwọn àjọ tó ń dáàbò àti mójútó àgbègbè ti orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà epa ní ọdún 1985 apá kẹrin tí wọ́n ṣe lẹ́yìn èyí pín sí fọ́lúmù méjì fọ́lúmù kínní ní wọ́n ti ṣàfikún ọ̀gangan àti agbègbè ojú àwọn ohun ìtúsóde àti fọ́lúmù kejì ṣàfikún ojú àwọn ohun ìtúsóde alágbèéká fọ́lúmù kínní lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí wà nínú apá karùn-ún àtẹ̀jáde ó sì wà lórí ẹ̀rọ ayélujára wọn ò mójútó fọ́lúmù kejì báyẹn mọ́ àmọ́ lílo ẹ̀bá-ọ̀nà láti fi ṣègbéléwọ̀n fún ìtúsóde àwọn ọkọ̀ lópòpónà àti láti arar àwọn ọkọ̀ tí wọn ò sí lópòpónà àti àwọn ohun èlò alágbèéká wà ní orí ẹ̀rọ ayélujára |
brila fm brila fm jẹ́ iléṣe igbogunsafefe erẹ idaraya tí wón dá sílè ní ọdún october 1 2002 larry izamoje jẹ́ oludasile iléṣe náà tí ó jẹ iléṣe igbohunasfefe erẹ idaraya àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè nigeria brila fm ní iléṣe mẹ́rin ní èkó abuja onitsha àti port harcourt iléṣe náà ṣẹṣẹ ṣe awijare ní kaduna ní ọdún 2014 fifa world cup wọn yan iléṣe náà gẹ́gẹ́ bí ọkan lára iléṣe mẹ́ta aṣáájú igbohunasfefe partners by optima sports management international |
fresh fm radio network in nigeria fresh fm jẹ́ nẹ́tíwọkì àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò ní nàìjíríà olayinka joel ayefele ló ni í àwọn ìbùdó fresh fm wà ní abẹ́òkuta adó-èkìtì àkúrẹ́ ìbàdàn èkó àti òṣogbo ìtàn ètò bẹ̀rẹ̀ ní ìbàdàn ní ọdún 2015 àti abẹ́òkuta ní ọdún 2018 ìbùdó adó-èkìtì bẹ̀rẹ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lọ́dún 2020nẹ́tíwọkì náà gbòòrò dé òsogbo ní oṣù kẹwàá ọdún 2021 àti sí èkó ní ọdún 2022 ìkànnì fún ìlorin ti jẹ́ dídá sílẹ̀ fresh fm ní ìbùdó ní gbogbo ìpínlẹ̀ gúúsù-ìwọ̀-oòrùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà nàìjíríà pẹ̀lú ìran lati gbòòrò dé àwọn agbègbè mìíràn ní ọjọ́ iwájú |
ife ìdílé family love jẹ́ nẹtiwọki rédíò aládani kan tí ó ní àwọn ibùdó mẹ́rin ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ ohùn ìní nípasẹ multimesh broadcasting company limited àwọn ibùdó wọ́n wà ní ìlú abuja port harcourt enugu ati umuahia multimesh gba ìwé-àṣẹ láti national broadcasting commission láti ní ilé-iṣẹ́ rédíò ni ọdún 2004 ibùdó port harcourt ni ó kọ́kọ́ ṣe ifilọlẹ ni ọdún 2005 ibùdó abuja bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2008 nígbàtí ilé-iṣẹ́ náà gba rédíò crowther ti tẹ́lẹ̀ umuahia sì tẹ̀lé ní ọdún 2012 ó kọ́kọ́ wà lóri 1039 mhz ní àkókò ti ibùdó enugu ṣe ifilọlẹ wọn ní oṣù kẹ́jọ ọdún 2017 |
cool fm nigeria cool fm nàìjíríà jẹ́ ilé-iṣé rédíò tó ń sọ èdè gẹ̀ẹ́sì ní nàìjíríà pẹ̀lú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà jákèjádò mẹ́rin nínú àwọn àgbègbè ìgbèríko mẹ́fà ní nàìjíríà o n ṣiṣẹ́ bíi cool tv àti rédíò orí ayélujára ilé -iṣẹ́ rédíò jẹ́ àgbéjáde àti àpáta fún àwọn òǹwòran àgbà ní ọdún 2019 cool fm gbàlejò ifọrọwanilẹnuwo pẹ̀lú cardi b èyí tí ó jẹ́ òfófóifọrọwanilẹnuwo náà wà ní orí afẹ́fẹ́ pẹ̀lú n6 àti temi balogun cardi b wà lórí ìrìn àjò àkọ́kọ́ rẹ̀ tí áfíríkà ó ń ṣeré ní naijiria ati ghana |
family love family love jẹ́ nẹtiwọki rédíò aládani kan tí ó ní àwọn ibùdó mẹ́rin ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ ohùn ìní nípasẹ multimesh broadcasting company limited àwọn ibùdó wọ́n wà ní ìlú abuja port harcourt enugu ati umuahia multimesh gba ìwé-àṣẹ láti national broadcasting commission láti ní ilé-iṣẹ́ rédíò ni ọdún 2004 ibùdó port harcourt ni ó kọ́kọ́ ṣe ifilọlẹ ni ọdún 2005 ibùdó abuja bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2008 nígbàtí ilé-iṣẹ́ náà gba rédíò crowther ti tẹ́lẹ̀ umuahia sì tẹ̀lé ní ọdún 2012 ó kọ́kọ́ wà lóri 1039 mhz ní àkókò ti ibùdó enugu ṣe ifilọlẹ wọn ní oṣù kẹ́jọ ọdún 2017 |
raypower raypower jẹ ẹgbẹ́ kàn tí àwọn ilé-iṣẹ rédíò aládánì tí nàìjíríà tí ń tàn káàkiri ní àwọn ìlú lọpọlọpọ jákèjádò orílẹ̀-èdè pẹlú lórí igbóhúnṣáfẹfẹ 1005 fm láti abuja àti ẹ̀kọ́ ìtàn ní àtẹ̀lẹ ifásílẹ̀ tí ìkéde lórí ọjọ kẹrin lè lógún oṣù kẹjọ ọdún 1992 daar communications plc tí ìpilẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ raymond dokpesi béèrè fún àti gbá ifọwọsile láti ṣíṣẹ ilé-iṣẹ rédíò òmìnira kàn ibusọ tí ó bẹrẹ̀ ìgbèjàdé ìdánwò ní ọjọ máàrùn dín lógún oṣù kejìlá ọdún 1993 ṣé ìtàn ní ọjọ kàn oṣù kẹsán ọdún 1994 nígbàtí ó bẹrẹ̀ igbóhùnsáfẹ́fẹ́ íṣòwò pẹlú ifilọlẹ raypower 1005 fm ní ìlú eẹ̀kọ́ gẹgẹ́ bí ibùdó ìṣẹ̀ igbóhùnsáfẹ́fẹ́ wákàtí mẹ́rin lè lógún àkọ́kọ́ ní nàìjííríà bákannáà bí ilé-iṣẹ igbóhùnsáfẹ́fẹ́ òmìnira aládánì àkọ́kọ́ nínú ìlú ibusọ abuja tí ṣe ifilọlẹ ní ọjọ kàn oṣù kínní ọdún 2005 ní oṣù karùn-ún ọdún 2019 ìgbìmò igbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí orílẹ̀-èdè tí ipá raypower àti ìkànnì tẹlìfísiọnu arábìnrin rẹ africa independent television dokpesi ẹní alátakò kàn sọ pé àwọn ibùdó rẹ ní ìfọkànsí àti pé àwọn ìdíyelé ìwé-àṣẹ tí ógajuigbimọ náà sọ pé ó fí àgbàrá mú pípadà wọn àìlófin nítorí ìrùfín àwọn koodù igbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti ikúna láti pàdé àwọn àdéhùn mìíràn sí olútọsọna náà ó yọkúrò àkíyèsí ìdádúró ní ópín oṣù náà |
futa radio futa radio ile-ise agbohun safefe ti futa 931 mhz fm ni ile-ise redio ti federal university of technology akure ni akure ondo state nigeria o bere ise ni 19 november 2010citation needed ni odun 2015ile ise redio naa jona nipase ijamba ina mo-na-mo-na awon akekoo ti won kawe ni ale ni won gbiyanju lati dekun ina naa ki o ma ba tan kojá ile-ise naa ati ofisi olu-gbaniwole ni fafiti naa itokasiedit source ^ kukogho samson august 25 2015 won padanu ohun to to milionu ni iye nipase ina mo-no-mo-no ti oganjo oru ni futa redio pulse nigeria retrieved august 29 2021 ^ ina nla ni inu ogba ile-ise agbohun safefe futa ba opolopo ogun ti o to milionu je sahara reporters august 24 2015 retrieved august 29 2021 stub icon 1 stub icon 2 |
inspiration fm community radio station in northampton united kingdom inspiration fm je rádíò ti ìlú ti o wa ni agbegbe northampton ni orile-ede united kingdom awón komuniti ni o n dari rádíò naa lati fi kó awón ará ilu lati fi da won lara ya ati lati fi ran awon ara ilu lowo si gbogbo northampton ni radio yii n de lati ibi ile-ise won ni northampton town center ni ibi ile-iwe northampton ni won ti gbe tirasimita won duro ti o wa ni àríwá ilu naa won sese gbe tirasimita naa lo goodwill solutions nibi molutin park industrial estate ìtàn nini 1994 ni inspiration fm bèrè nigba ti awón karibian ti won jo feran awón nkan idarawaya wa papo lati bere radio naa ni 18november titi di 15 december 1996 ni won bere isoro si afefe ti ijoba lowo si ni 1997 won fi awón ara ilu giriki kun radio naa ni 2000 inspiration fm bèrè awón idaraya fun gbogbo ilu ti won si pe awon ol ni 2004 won fun radio naa ni queen's golden jubilee award for voluntary service by groups in the community references the roots of inspiration fm are as a pirate radio station that first started in 1994 as a result of collaboration between young men and women of african caribbean descent who shared a passion for music dance and communication the ‘inspiration family’ as they have become known identified the needs of the diverse northamptonshire communities who were under-represented in media programmes on this community radio station are multicultural and tailored to reflect its mainly punjabi african and irish listeners working with organisations including local councils the council for ethnic minority communities abroadcastingnd the black policeman’s association means that this project has moved beyond negative images and now creates positive role models for all young people with over 60 volunteers and 8 committee members weekends and evenings are spent working with others especially young people encouraging them to use their spare time in a positive constructive manner inspiration fm's first legal broadcast was from 18 november to 15 december 1996 on a 28-day restricted service licence rsl and since then it has been on-air on a total of 15 rsls a show for the greek community was added to the station's line up in 1997 the first and only show of its kind outside london and the station was included among the limited number of rsl stations who were allowed to broadcast during the millennium celebrations in 2000 inspiration fm's mark dean was approached by bbc radio northampton's editor about presenting a programme to reach all sectors of the community and the show inspirations was formed with marks strong links within the community the inspirations show has been going strong covering hard hitting local and international news and guest stars like beyoncé the somali community show began in 2003 and a polish community show was included in 2007 to cater for the large influx of poles to northampton after poland joined the eu in 2004 in 2004 the organisation was awarded the queen's golden jubilee award for voluntary service by groups in the community on 24 july 2008 inspiration fm was awarded a 5-year community radio licence by ofcom and began 24/7 broadcasts when it was officially opened by northampton mayor marianne taylor on saturday 24 july 2010 dj mkhukhwini became a regular guest on bbc radio 1xtra after he was spotted presenting the african community show on inspiration fm since 2011 jason d lewis fri 8-11pm featured on capitalxtra in the guest mix on robert bruce's homegrown 4-7pm show on saturday 16 march 2019 programmes broadcasts from inspiration fm's studios in sheep street northampton include popular genres like rb reggae gospel rap funk dance old skool soul music asian african greek eastern european and irish folk music the local band review show on a wednesday evening and a regular children's show on saturday mornings programming is aimed at representing areas of the community that are currently under-represented by mainstream radio this includes the afro-caribbean irish and asian although many more are also represented including children the policy of inspiration fm multi-cultural in its programming for the people by the people on friday’s 6-8pm ‘the dance music show with mark manning’ supported by gehric barreau of gt-systems jason d lewis friday 8-11pm plays new hip hop rap uk rnb dancehall and afrobeats jason d lewis featured on capitalxtra in the guest mix on robert bruce's homegrown 4-7pm show on saturday 16 march 2019 activities inspiration fm is a major sponsor of the northampton carnival and one of inspiration fm's founding members mark dean sits on the organising committee inspiration fm produces the inspirations afro-caribbean show for bbc radio northampton |
rhythm 937 fm port harcourt rhythm 937 fm jẹ́ rédíò ti iṣowo tí ó wà ní agbègbè old gra ti port harcourt ìpínlẹ̀ rivers ilé iṣẹ́ rédíò yìí á máa ṣe àwọn ìkéde òde òní wọ́n a máa gbé orin onírúurú síi bíi rb hip hop pẹ̀lú orin-ijó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àti reggae o jẹ ohun ini ati ẹ̀ka ìṣiṣẹ́ silverbird communications lábẹ́ ilé-iṣẹ́ silverbird group àti pé ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ilé-iṣẹ rédíò aládàáni tí ó lókìkí jùlọ ní ìhà gúúsù orílẹ̀-èdè nàìjíríà òṣìṣẹ́ dísíkí jokì dj tan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òfin ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kejìlá ọdún 2005 méjì nínú àwọn olóòtú rédíò klem ofuokwu àti cleopatra tawo ni wọ́n mú tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn pé wọ́n sọ ìròyìn irọ́ nípa ìkùnà afárá wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n fún ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ni wọ́n dá wọn sílẹ̀ lórí ẹ̀wọ̀n |
dessel locomotive factory |
radio lagos brila fm |
aso radio aso radio 935 fm jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò ilẹ̀ nàìjíríà tó fìdí kalẹ̀ sí abuja ìjọpa àpapọ̀ ló sì ń darí rẹ̀ ìyẹn federal capital territory wọ́n dá ilé-iṣẹ́ rédíò yìí sílẹ̀ ní ọdún 1997 ẹni tó ṣagbátẹrù rẹ̀ ni rtd brigadier eneral jeremiah timbut useni tó fìgbà kan jẹ́ mínísítà abuja nígbà náà studio àti ẹ̀rọ ìgbéròyìn-sáfẹ́fẹ́ wà ní orí-òkè katampe pẹ̀lú àtúngbéjáde rẹ̀ ní karshi abaji àti bwari ní ọjọ́ 19 oṣù karùn-ún ọdún 1999 rtd general mamman t kontagora tó jẹ́ mínísítà federal capital territory fi àṣẹ sílẹ̀ láti ṣí ilé-iṣẹ́ ìgbéròyìn-sáfẹ́fẹ́ náà tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu wọ́n kéde ìkànni ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní aso tv ní ọdún 2008 àmọ́ kò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ títí wọ ọdún 2012 lákòókò tí ilé-iṣẹ́ náà jẹ́ ti ìjọba aso tv máa ń rówó látàri ìpolówó |
sobi fm sobi fm 1019 mhz jẹ́ ilé-iṣẹ́ rédíò kan tó wà ní ìlú ilorin ní ìpínlẹ̀ kwara ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà wọ́n ṣèdásílẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ọdún 2017 ó sì wà ní orí-òkè sobi ní òpópónà shao olùdásílẹ̀ olùdásílẹ̀ sobi fm ni lukman akanbi olayiwola mustapha tó jẹ́ olóṣèlú ilẹ̀ nàìjíríà àti òṣìṣẹ́ báǹkì |
nigeria custom broadcasting network nẹtiwọọki broadcasting customs nigeria ncbn jẹ́ apá mídíà tí ilé -iṣẹ́ kọ́sítọ́mù nàìjíríà tí a gbèrò láti ṣiṣẹ́ rédíò àti àwọn ibùdó ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ní àwọn ìlú pàtàkì káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè lọwọlọwọ ó tàn káàkiri lórí rédíò 1067 mhz fm àti ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ní abuja ní ọdún 2020 ncs wọ inú àjọṣepọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ aládánì kàn láti ṣe ìrànlọ́wọ́n fún ìdàgbàsókè tí rédíò fm àti àwọn iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgbègbè ìṣàkóso mẹ́fà tí orílẹ̀ èdè pẹ̀lú ibi-afẹde tí “atunkọ ncs ìgbéga àwọn àyè ìṣòwò àti jíjẹ́ ààbò ìmòye ní nàìjíríà fun agbẹnusọ fún ilé-ibẹwẹ ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán àti iṣẹ́ rédíò nílùú abuja àti èkó ni wọ́n ṣe àtòjọ gẹ́gẹ́ bí ipò tó ga jù lọ |
melissa barrera melissa barrera martínez tí a bí ní ọjọ́ kẹrin osù keje ọdún 1990 jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ èdè èdè mexico ní orílẹ̀ èdè mexico wọ́n mọ́ fún ipa rẹ̀ nínú àwọn eré bi siempre tuya acapulco 2013 tanto amor 2015 àti club de cuervos 2017 káàkiri àgbáyé wọ́n mọ́ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi samantha carpenter nínú fìímù scream àti gẹ́gẹ́ bi starz nínú eré vida ìpìlẹ̀ rẹ̀ wọ́n bí barrera ní ìlú monterrey mexico ìlú náà ni wọ́n ti tọ dàgbà ó kàwé ní ilé ìwé orin kan ní new york university tisch school of the arts |
jasmin savoy brown jasmin savoy brown jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orilẹ-èdè amẹ́ríkà ó ṣeré nínú fíìmù hbo tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ the leftovers 20152017 eré abc tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ for the people 20182019 àti eré showtime tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ yellowjackets 2021present ó tún ṣeré nínú àwọn fíìmù bi sound of violence 2021 scream 2022 àti scream vi 2023 ìpìlẹ̀ wọ́n bí brown sí ìlú alameda california wọ́n sì to dàgbà ní ìlú springfield oregon nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún merin brown kópa nínú orin kan ní ilé ìjọsìn tí ó ń lọ èyí sì mú kí ó ní ìfẹ́ sí eré ṣíṣe bí ó ti ń dàgbà ó kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin àti eré lẹ́yìn ìgbà tí ó parí ìwé mẹ́fà ó kó lọ sí portland oregon láti lépa àlá rẹ̀ nínú eré ṣíṣe |
akure ofosu forest reserve ibi ipamọ igbo akure ofosu wa ni guusu ìwọ oòrùn ni orile ede nàìjíríà o si bo ẹ̀rin lé ní ẹ̀wá dín-ní-irinwó onigun mẹrin kilomita akure ofosu ṣe pataki pupọ fun itoju awọn olugbe elegbede ni nàìjíríà iwadi ti a ṣe lakoko ọdun 2007 ri awọn itẹ ẹtalelọgbọn ni awọn ipo mẹrin laisi iran taara itan ti iṣeto ni ọdun 1936 ati pe o ni nkan bii irinwó onigun mẹrin kilomita 154 square miles reserve forest akure-ofosu tun ni bode ala owo ohosu ati '/ papọ ti o jẹ ọkan ninu awọn agbegbe ti o tobi julọ ti igbo ti o ku ni nigeria awọn igbo ti o wa laarin jẹ ile si ọpọlọpọ awọn oriṣiriṣi oriṣiriṣi pẹlu awọn primates ti o ni ewu mangabeys pupa-capped cercocebus torquatus nigerian funfun-throated guenons cercopithecus erythrogaster pococki putty-nosed obo cercopithecus nictitans mona ọbọ cercocebus mona ati awọn miran gbogbo le ṣee ri ni ohun ti o ku ti akurest-ofoss' |
àwòrán àwòrán jẹ́ ìfirọ́pò ohun tí a lè f'ojú rí ó lé wá ní ọ̀nà méjì tàbí mẹ́ta tàbí kí á wò ó nínú ohun tí a fi ń wo àwòrán tí ó fi lè fún wa ní ìtumọ̀ àwòrán náà gan an àwòrán lè jẹmọ́ ohun ìṣẹ̀mbáyé tí a yá kalẹ̀ pẹ̀lú kò di dandan kí àwòrán ó fi gbogbo ara hànde kàá tó mọ̀ wípé àwòrán ni àpẹẹrẹ irúfẹ́ àwòrán bẹ́ẹ̀ ni èyí tí ó wà níbí tí ó fi apá kan hàn nínú àwọ̀ rẹ̀ tí èyí sì fi gbogbo èyí tókù hàn bí àwòrán bá ní àwọ̀ funfun ati dúdú síbẹ̀ àwòrán yí yóò sì sọ ohun tí ó bá jẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a kò rí gbogbo ara rẹ̀ pátá ojúkan ni àwòrán ma ń wà bákan náà àwòrán ti ń lọ bọ̀ láyé òde òní àbùdá àwòrán àwòrán lé jẹ́ onígun méjì tàbí mẹ́ta tàbí kí á wò ó nínú ohun tí a fi ń wo àwòrán tí ó fi lè fún wa ní ìtumọ̀ àwòrán náà gan an àwòrán lè ní ojú ìwò tàbí mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí a fi kámẹ́rà yà àwọn lé jẹ́ onígun mẹ́ta bíi ère tàbí hólógíráámù wọ́n lè fi àwọn irinṣẹ́ bí kámẹ́rà dígí tàbí iwo gbe tí wọ́n fi ń wo àwọn kòkòrò àìfojúrí tí ojú lásán kò lè rí |
devyn nekoda devyn nekoda tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejìlá ọdún 2000 jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀ èdè canada ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré láti ìgbà èwe rẹ̀ ó sì tún ṣeré nínú fíìmù scream vi tí wọ́n ṣàgbéjáde ní ọdún 2023 ìpìlẹ̀ rẹ̀ wọ́n tọ́ nekoda dàgbà ní ìlú brantford ontario ibẹ̀ náà ni wọ́n ó ti lọ ilé ìwé ó jẹ́ ọmọ ọdún méjì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ ijó jíjó ní ìlú simcoe ontario |
kámẹ́rà kamẹ́rà jẹ́ àpótí rébété tí ó ní ojú tí a lè fi yan àwòrán yálà àwòrán onígun méjì tàbí mẹ́ta gbogbo àwọn kámẹ́rà ni wọ́n ma ń jẹ́ àpótí rébété kan tí a kàn pa tí ó ní ihò bíntín tí oyè ìmọ́lẹ̀ lè gbà kọjá láti gba àwòrán sílẹ̀ sínú díígí tí wọ́n ti ṣepa sínú rẹ̀ kámẹ́rà ní àwọn irinṣẹ́ kan tí wọ́n ma ń lò láti fi ya àwòrán ní àsìkò tí kò bá sí inọ́lẹ̀ tó já geere lára rẹ̀ ni lẹ́nsì tí wọ́n sopọ̀ mọ́ àpótí kámẹ́rà náà lára rẹ̀ náà ni ìrìnṣẹ́ tí wọ́n ń pe ní shutter speed èyí ni ó ma ń ka iye àsìkò àti eré tí mọ̀nà-mọ́ná gbà keje nínú kámẹ́rà náà àwòrán tí ó dúró bọrọgidi ni won sábà ma ń fi kámẹ́rà yà ba kan náà ni wọ́n ti ń fi kámẹ́rà ya àwọn àwòrán tí wọ́n ń lọ tí wọ́n bọ̀ irúfẹ́ àwọn àwòrám tí wọ́n ń lọ bọ̀ yí a wọ́n ń ṣàkójọ rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe fíímù agbéléwò tàbí sinimá |
imí ọjọ́ chemical element with atomic number 16 imí ọjọ́ tabí sulfur sulphur ní èdè brítènì ni ó jẹ́ kẹ́míkà tí a ma ń ṣe àdámọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àmì s tí númbà rẹ̀ jẹ́ 16 imí ọjọ́ jẹ́ ìkan nínú àwọn kẹ́míkà tí tí ó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ àgbáyé àpapọ̀ imí ọjọ́ ati átọ́mù ni ó lábẹ́ oru tí kò lágbára ni ó ma ń yíra padà sí cyclic octatomic molecules tí ètò ìyípadà rẹ̀ ń jẹ́ s8 àwọn kẹ́míkà tí wọ́n kórajọ di imí ọjọ́ ni wọ́n ma ń ní àwọ̀ oòrùn rẹ́súrẹ́su tí ó sì ma ń le koko nígbà tí ó bá wà ní abẹ́ ilé tí kò sí oòrùn imí ọjọ́ jẹ́ ìkan lára àwọn kẹ́míkà mẹ́wá tí ó pọ̀ jùlọ lágbàáyé tí ó sì jẹ́ ẹlẹ́karùn un tí ó pọ̀ jùlọ ní orí ilẹ̀ ayé wọ́n ma ń rí imí ọjọ́ ní ọ̀pọ̀ yanturu ní orí ilẹ̀ agbáyé wọ́n sì dá a mọ̀ ní ayé atijọ́ ní àwa ìlú bíi china india àti greece tí ó fi mọ́ egypt gẹ́gẹ́ bí ohun èlò gidi fún ìlera wọn nínú ìtàn wọ́n ṣe akọsílẹ̀ oríṣiríṣi ní imí ọjọ́ nínú ìmọ̀ lítíréṣọ̀ tí wọ́n sì fun ní orúkọ brimstone which means burning stone láyé òde òní orísiríṣi ohun èlò ni wọ́n ń fi imí ọjọ́ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ àwọn èròjà alágbára tí ó léwu kúrò nínú rẹ̀ wọ́n ń lo imí ọjọ́ fún ìpèsè àwọn orísiríṣi nkan bíi ajílẹ̀ sulfuric acid ati àwọn nkan miran wọ́n m ń lo imí ọjọ́ nínú ìmọ̀ ìṣirò wọ́n ń lòó láti fi pèsè oògùn ẹ̀fọn ati àwọn àwọn oògùn apakòkòrò míràn púpọ̀ nínú àwọn èròjà inú imí ọjọ́ ni wọ́n ní òórùn nígbà tí àwọn òórun wọn jẹ́ àdámọ́ wọn àwọn òórùn bíi òórùn omi ọsàn ata ilẹ̀ ìdí ni wípé àwọn èròjà wọ̀nyí jẹ́ àdámọ́ rẹ̀ èyí tí ó jẹ́ hydrogen sulfide ni ó ma ń mú òórùn bí ẹyin tí ó ti di òbu jáde látàrí àdámọ́ rẹ̀ imí ọjọ́ jẹ́ ohun pàtàkì fún gbogbo ohun abẹ̀mí |
jenna ortega jenna marie ortega tí a bí ní ọjọ́ ọjọ́ kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹsàn-án ọdún 2002 jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè amẹ́ríkà ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré nínú àwọn fíìmù láti ìgbà èwe rẹ̀ ó sì gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ nínú eré jane the virgin 20142019 ó gbajúmọ̀ si lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ó ṣe harley diaz nínú eré disney kan stuck in the middle 20162018 ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ imagen award fún ipa rẹ̀ nínú fíìmù yìí ó tún kópa ellie alves nínú fíìmù you ní ọdún 2019 àti nínú fíìmù yes day 2021 tí netflix ṣe ortega kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù bi the fallout 2021 scream àti x méjèèjì ní ọdún 2022 àti scream vi ní ọdún 2023 ní ọdún 2022 ó kópa wednesday addams nínú fíìmù netflix tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ wednesday èyí sì mú kí wọ́n yàn fún àwọn tí ó le gba àmì-ẹ̀yẹ golden globe àti screen actors guild awards ìpìlẹ̀ wọ́n bí jenna marie ortega ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹsàn-án oṣù 2002coachella valley ní california ni wọ́n bí sí òun ni ọmọ kẹrin nínú mẹ́fà bàbá rẹ̀ wá láti mexico ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ mexico àti puerto rica |
ajílẹ̀ ajílẹ̀ ni a lè pè ní èròjà tí a ṣe yálà nílàna ìgbàlódé ni tàbí ti àbáléyé tí a wá dá tabí pòó mọ́ ilẹ̀ láti lè jẹ́ kí ilẹ̀ ó ní agbára láti mú ohun ọ̀gbìn jáde dára dára ju t'àtẹ̀yìnwá lọ a lè ṣe ajílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ohun èlò nílé iṣẹ́ ìgbàlódé tàbí kí á ṣe é pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìbílẹ̀ nípa iṣẹ́ ọ̀gbìn ìgbàlódé wọ́n ma ń lo èròjà nitrogen n phosphorus p àti potassium k tí wọ́n sì ma ń fi èròjà rock flour kun kí ó lè rú gọ́gọ́ àwọn àgbẹ̀ ma ń po ajílẹ̀ mọ́ iyẹ̀pẹ̀ nípa kí wọ́n wọn sí orí ilẹ̀ tàbí kí pòó mọ́ omi tàbí kí wọ́n fi ọwọ́ pòó mọ́ iyẹ̀pẹ̀ |
arewa 24 arewa24 jẹ́ ìkánni tẹlifisiọnu satẹlaiti nàìjíríà tí o wà lóri dstv gotv àti startimes tí o ṣé àfihàn ìgbésí ayé tí agbegbe ariwa nigeria o jẹ́ ìkánni ọ̀fẹ́ sí afẹ́fẹ́ àkọ́kọ́ láti lo ede hausa |
nigerian television authority aláṣẹ telifísọ̀nù ti nàìjíríà tàbí nta jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáféfé ti ìjọba tí ó jẹ́ ti ìjọba nàìj́iríà àti apákan ti ìṣòwò lá àkọ́kọ́ tí a mọ̀ sí ni nigerian television ntv ó ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ní ọdún 1977 pẹ̀lú àṣẹ kan lórí ìgbóhùnsáféfé tẹlifísiọnu orílẹ̀-èdè lẹ́hìn gbígbà àwọn ilé-iṣẹ́ tẹlifísọ̀nù agbègbè nípasẹ̀ àwọn aláṣẹ ìjọba ológun ní ọdún 1976 lẹ́hìn ìdínkù àǹfàní láti ọ̀dọ gbogbo ènìyàn ní sísètò tí ìjọba tí ó ní ipa ó pàdánù anìkanjọpọ́n rẹ lórí ìgbóhùnsáféfé tẹlifísiọ̀nù ni nàìjíríà ni àwọn ọdún 1990 nta ń ṣiṣẹ́ nẹ́tíwọ́ọ̀kì tẹlifísiọ̀nù tí ó́ tobi jùlọ ni nàìjíríà pẹ̀lú àwọn ibùdó ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà ní orílẹ̀-èdè náà òpòlopò ènìyàn ni a kà sí bi “ohùn ojúlówó” ti ìjọba nàìjíríà ìtàn ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ibùdó ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní nàìjíríà ilé-iṣẹ́ amóhùnmáwòrán àkọ́kọ́ ní nàìj́iríà ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìjọba iwọ̀-oòrùn nàìj́iríà wntv bẹ̀rẹ̀ ìgbéjáde ní ọjọ́ 31 oṣù kẹwàá ọdún 1959 alága àkọ́kọ́ rẹ ni olápàdé òbísèsan agbẹjọ́rò kan tí ó gba ẹ̀kọ́ ni ìlú gẹ̀ẹ́sì àti ọmọ akínpèlú òbísèsan àwùjọ ìbàdàn àti alákòóso àkọ́kọ́ ti báǹkì cọpurétìfù ti nàìjíríà vincent maduka onímọ̀ẹ̀rọ kan tẹ́ lẹ̀ rí jẹ́ alákòsóo gbogbogbò ibùsọ̀ náà wa ni ilú ìbàdàn eyiti o jẹ ki o jẹ ibudo igbohunsafefe akọkọ ni afirika tropical botilẹjẹpe diẹ sii awọn ẹya ariwa ti afirika ti ni awọn ibudo tẹlifisiọnu tẹlẹ ní oṣù kẹ́ta ọdún 1962 radio-television kaduna/redio kaduna television rktv ti dasilẹ o wa ni kaduna ati pe o ṣiṣẹ nipasẹ ile-iṣẹ broadcasting ti northern nigeria rktv tun pese agbegbe fun awọn ipinlẹ ariwa ariwa o ṣi awọn ibudo tuntun lori zaria ni oṣu keje 1962 ati lori kano ni kínní 1963 igbamiiran ni 1977 o ti tun-iyasọtọ ntv-kaduna |
ogun state television tẹlifíṣọ̀n ìpínlẹ̀ ògùnogun state television tí a tún mọ̀ sí ogtv jẹ́ ilé-iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ó jẹ́ ti ìjọba ìpínlẹ̀ ògùn ó jẹ́ dídásílẹ̀ ní oṣù kejìlá ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọdún 1981 gẹ́gẹ́ bí i ilé-iṣẹ́ gbogboogbò comrade tunde oladunjoye ni ó jẹ́ alága ìgbìmò ilé-iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n náà |
emmanuel tv emmanuel tv jẹ́ nẹ́tíwọkì tẹlifísàn onígbàgbọ́ pẹ̀lú olú ile ní ìpínlẹ̀ èkó nàìjíríà t b joshua ni olùdásílẹ̀ rẹ̀ òun ni olùṣọ́-àgùntàn àgbà àtijọ́ ti synagogue church of all nations scoan ní ìpínlẹ̀ èkó nàìjíríà ó' tún jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀rọ ayélujára iṣẹ́-ìránṣẹ́ kìrìtẹ́nì tí ó ṣe alábàápín jùlọ lóri youtube ní káríayé pẹ̀lú àwọn alábàápín tí ó ju ọ̀kẹ́ kan lọ ní oṣù kínní ọdún 2019 ìtàn ní ìparí àwọn ọdún 1990 scoan bẹ̀rẹ̀ gbígba àkíyèsí àgbáyé látara pínpín àwọn kásẹ́ẹ̀tì fídíò tí ń ṣàfihàn àwọn àgékúrú iṣẹ́-ìránṣẹ́ àkọ́kọ́ ti joshua àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a sọ ní àfíkún si ijoshua bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ìtọlẹ́sẹẹsẹ ìgbà gbogbo jáde tí wọ́n sọ pé ó ń fi àwọn iṣẹ́ ìyanu hàn lóri ẹ̀ |
african magic african magic jẹ́ fọ́omù ìdàgbàsókè àti iṣẹ́ idán láàárín àṣà àti àwùjọ tí áfíríkà àti àwọn àjèjì ìtumò ọ̀rọ̀ idán ọ̀rọ̀ idán lè rọrùn ní òye bíi ìtọ́kasí ìṣàkóso tí àwọn ipá ti iṣẹ ṣiṣe kò wúwo ní ìhùwàsí ó sí jẹ́ iṣẹ ṣiṣe didoju lati ibẹrẹ iṣe idan sùgbón nipasẹ ifẹ ti alalupayida ni ero lati di ati lati ni abajade ti o duro bóyáo dára tàbí búburú buburu ni ibatan si ajẹ ek bongmba wa ajẹ oracles ati magic laarin azande nipasẹ evans-pritchard ti a tẹjade 1937 ti o ni iduro fun idinku ninu riri iye idan bi koko-ọrọ ti ikẹkọ peter pels 1998 sọ pe o kuna ni ironu bakanna ti o jẹyọ lati aifọwọyi ti ko tọ si abala odi ti ajẹ ti o nsoju totum ti idan |
arise news awọn iroyin arise jẹ́ ìkánni ìròyìn àgbáyé tí ó dá lórí ìlú lọ́ńdọ̀nù ó ní àwọn ilé -ìṣèré ní ilu new york london johannesburg abuja àti eko ìkánni náà ṣe àfihàn àkóónú áfíríkà amerika àti yuroopu arise broadcasting ltd ni ó ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ èyítí ó jẹ́ ohun ìní nípasẹ̀ onímọ̀ràn oníròyìn nàìjíríà nduka obaigbena ní oṣù kẹwàá ọdún 2017 àwọn ìròyìn arise wa lórí ìkánni 416 lórí dstv ní nigeria ní oṣù kàrún ọjọ́ 2020 àwọn ìròyìn dìde ni a lè ríi ṣíṣánwọlẹ́ lórí freeview nípasẹ̀ iṣẹ́ tirẹ̀ lórí ìkánni 269 àti gẹ́gẹ́ bí apákan ti visiontv ìlà lórí ìkánni 264 arise tún ṣiṣẹ́ ìkánni kejì lórí visiontv tí à npé ní live 360 ìkánni yìí jẹ́ ìdójúkọ díẹ̀ sii lórí eré ìdárayá pẹ̀lú àwọn iṣàfihàn àṣà tí ó jọra sí àwọn ti fashiontv àti edgy tv àti eré ìdárayá pẹ̀lú ìgbóbòhúnsáfẹ́fẹ́ ere-ije greyhound lórí ìkánni títí di ọdún 2021 nígbàtí sporty stuff hd lórí ìkánni freesat 250 gba àwọn ẹ̀tọ̀ ni ọjọ 9 kínní 2022 ile-iṣẹ tun ṣe iyasọtọ live 360 bi arise play orukọ kanna gẹgẹbi iru ẹrọ ṣiṣanwọle ile-iṣẹ naijiria a ṣe ifilọlẹ iṣẹ arise play ni ọdun 2021 ati pe o ni nọmba awọn akọle lati bbc studios ninu iwe akọọlẹ rẹ pẹlu awọn iṣelọpọ bii luther small ax famalam ẹgbẹ akọkọ britain itan igbagbe ati hey duggee ti o wa fun awọn alabapin orilẹ-ede naijiria |
akbc akwa ibom state broadcasting corporation kikuru akbc uhf channel 45 jẹ́ ilé-iṣẹ́ tẹlifísíọ̀nù ti ìjọba ní uyo akwa ibom akwa ibom broadcasting corporation jẹ́ dídá sílẹ̀ ní ọjọ́ 4 oṣù kẹrin ọdún 1988 àti pé ó jẹ́ àkọ́kọ́ àti ìbùdó tẹlifíṣíọ̀nù agbègbè nìkan akbc pese tẹlifísíọ̀nù méjèèjì àti àwọn iṣẹ́ rédíò ó ń darí ní 90528mhz akbc tẹlifísíọ̀nù tàn káàkiri láti ntak inyang ọdún 1991 ní gómìnà ipinle akwa ibom ìyẹn idongesit ṣí ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn náà sílẹ̀ |
silverbird group silverbird group jẹ́ ilé-iṣẹ́ mídíà pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka ní rédíò tẹlifíṣọ̀nù ilẹ̀ títà àti àwọn sinimá tí ó jẹ́ olú ilé-iṣẹ́ ní èkó orílẹ̀-èdè nàìjíríà ilé-iṣẹ́ náà jẹ́ dídásílẹ̀ ní ọdún 1980 nípasẹ̀ ben murray-bruce àti pé ó ka àwọn sinimá silverbird àti mbgn àti láàárín awọn ohun-ìní rẹ̀ àwọn ìpín ìṣòwò rẹ̀ jẹ́ silverbird properties silverbird film distibution silverbird communications silverbird cinemas silverbird production àti dream magic studios ní oṣù kọkànlá ọdún 2022 ilé-iṣẹ fowó sí ìwé àdéhùn ìnáwó 145 mílìònù kan pẹ̀lu láti kọ́ ben murray-bruce studios àti ilé-ẹ̀kọ́ fíìmù bmb studios and film academy ní ní èyítí a ròyìn pé ó jẹ́ ti ìwọ̀-oòrùn áfíríkà tí ó tóbi jùlọ n í ti èkó àti fíìmù ṣíṣe ìtàn awọn ipilẹṣẹ ti ile-iṣẹ bẹrẹ ni oṣu karun ọdun 1980 nigbati benedict murray-bruce ọmọ alaṣẹ uac kan tẹlẹ ni aabo awọn owo lati ọdọ ẹbi rẹ lati bẹrẹ ile-iṣẹ igbega orin kan iṣowo naa bẹrẹ lakoko olominira keji ti nigeria ati pe o ni ipa ninu igbega awọn oṣere orin amẹrika ni nigeria ile-iṣẹ ti ṣeto awọn igbega fun iru awọn ẹgbẹ bii the whispers shalamar lakeside ati carrie lucas ile-iṣẹ naa nigbamii lọ sinu idije ijó kan awọn ẹgbẹ nigbamii ti fẹ sinu ẹwa pageant |
africa independent television africa independent television tí a tún mọ̀ nípa àdàpè rẹ̀ ait jẹ́ olùgbúhùnsáfẹ́fẹ́ tẹlifísàn ti aládàáni ní nigeria ó ń ṣiṣẹ́ láì sanwó gbọ ní nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí aládàákọ́ tó tóbi jù lọ nẹ́tíwọ́kì tẹlifíṣan orí ilẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé iṣẹ́ ní mẹ́rìnlélógún nínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ní nàìjíríà ait tun jẹ ikede nipasẹ satẹlaiti tẹlifisiọnu lati olu-iṣẹ iṣẹ rẹ ni abuja ait jẹ oniranlọwọ ti daar communications plc ti o wa jakejado afirika ati nipasẹ nẹtiwọọki dish si ariwa america ní united kingdom àti ireland ó wà lóri ìkànnì sky 454 gẹ́gẹ́ bí ìkànnì onígbígbọ́ ọ̀fẹ́ kọ ó jẹ́ èyí tí wọn máa ń sanwó gbọ́ títí dé august 1 2016 wọ́n ṣe àfikún ìkànnì tí à ń pè ní ait movistar tí ó wà lóri ìkànnì sky 330 dẹ́kun ìgbesáfẹ́fẹ́ ní 28 july 2009 ait international ti dẹ́kun ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní united kingdom àti ireland ni ọjọ́ 15 oṣù kẹwàá ọdún 2019 paade oludasile raymond dokpesi ṣe itọsọna ijakadi alaafia si apejọ orilẹ-ede lori 6 okudu 2019 lati fi ẹbẹ kan ti o beere fun atunyẹwo ti awọn ofin igbohunsafefe raymond dokpesi ti ni ni iṣaaju pe akiyesi awọn oniroyin si kikọlu olootu awọn irokeke ijẹniniya ati aiṣedeede iṣelu nipasẹ oludari gbogbogbo modibbo kawu ti national broadcasting commission nbc ti o ni laipe yii ti dije idibo alakọbẹrẹ gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ oselu all progressive congress fun ipo gomina ni ipinlẹ kwara dokpesi tun fi ẹsun kan pe nbc n ṣiṣẹ lori aṣẹ ti ile-igbimọ aarẹ orilẹ-ede naijiria lati dina lori nẹtiwọki tv nitori ẹsun ti ilodi si koodu igbohunsafefe |
samara weaving samara weaving tí a bí ní ọjọ́ kẹtalélógún oṣù kejì ọdún 1992 jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀ èdè austrilia ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré rẹ̀ nípa kíkó ipa kirsten mulroney nínú out of the blue 2008 ó gbajúmọ̀ nígbà tí ó kó ipa indi walker nínú eré home and away 20092013 èyí tí ó gba àmì-ẹ̀yẹ australian academy of cinema and television arts aacta fún ni ẹ̀ka obìnrin láàrin ọdún 2015 sí ọdún 2023 ó kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré àwọn eré bi ash vs evil dead 20152016 àti smilf 20172019 ní ọdún 2017 ó tún ṣeré nínú àwọn fíìmù bi mayhem the babysitter àti three billboards outside ebbing missouri ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ a screen actors guild award fún ipa rẹ̀ nínú fún three billboards outside ebbing |
the guardian nigeria the guardian jẹ́ ìwé-ìròyìn ojoojúmọ́ olómìnira ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1983èyí tí ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn guardian tó wà ní ìpínlè eko ní nàìjíríà ìtàn ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn the guardian jẹ́ dídá sílẹ̀ ní ọdún 1983 láti ọwọ́ alex ibru ẹni tí ó jẹ́ oníṣòwò àti stanley macebuh tó jẹ́ akọ̀ròyìn pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn daily times ti wọ́n dá ilé-iṣẹ́ yìí sílẹ̀ láti máa ṣe àgbéjáde ìròyìn tó kúnjú òṣùwọ̀n jáde pẹ̀lú àwọn olóòtú tó jí pépé wọ́n kọ́kọ́ ṣe àgbéjáde ìwé-ìròyìn yìí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kejì ọdún1993 gẹ́gẹ́ bíi ìwé-ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tó máa ń jáde ní ọjọ́ àìkú lásìkò ìṣèjọba muhammadu buhari àwọn ajábọ̀-ìròyìn ìyẹn tunde thompson àti nduka irabor ni wọ́n rán lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ọdún 1984 lábẹ́ ìfilélẹ̀ kẹrin ti ọdún 1984 èyí tẹrí òmìnira àwọn akọ̀ròyìn mọ́lẹ̀ |
complete sports complete sports jẹ́ ìwé-ìròyìn eré-ìdárayá orílẹ̀-èdè nàìjíríà lójoojúmọ́ ó sì ní orílé-iṣẹ́ rẹ̀ ní isolo ìjọba ìbílẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ èkó ọdún 1995 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ ẹ́ jáde gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìròyìn ti complete communications limited àti pé ó ti di ọ̀kan lára àwọn ìwé-ìròyìn tó pọ̀ jù lọ ní naijiria ìwé-ìròyìn náà dojú dé sí àwọn eré-ìdárayá naijiria pàápàá àwọn agbábọ́ọ̀lù nàìjíríà complete sports ti pín káàkiri orílẹ̀-èdè naijiria àti díẹ̀ nínú àwọn agbègbè ti benin àti cameroon nítorí náà ó mu kí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwé-ìròyìn tí ó káàkiri jù lọ ní ìwọ-oòrùn afirika |
ẹgbẹ silverbird |
awọn iroyin dide |
hayden panettiere hayden lesley panettiere tí a bí ní ọjọ́ kanlelogun oṣù kẹjọ ọdún 1989 jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ orílẹ̀ èdè amerika ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi claire bennet nínú eré heroes 20062010 àti gẹ́gẹ́ bi juliette barnes nínú eré nashville 20122018 ó gba àmì ẹ̀yẹ méjì fún golden globe award for best supporting actress series miniseries or television film ó tún kópa nínú fíìmù scream òun ni ó kópa kirby reed nínú fíìmù náà ó jẹ́ ọmọ bíbí palisades new york ó kọ́kọ́ hàn lórí ẹ̀rọ ìmóhùn máwòrán nínú ìpolówó kan ní ọdún 1990 nígbà tí ó jẹ́ ọmọ oṣù mọ́kànlá ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré ní pẹrẹwu nígbà tí ó kó ipa sarah roberts nínú fíìmù one life to live láti ọdún 1994 sí ọdún 1997 |
online tiketi online tiketi alaye tikẹti ori ayelujara ni ọna ti o rọrun ati mimọ fojuinu pe o fẹ gba ibikan ni lilo ọkọ oju-irin ilu bii ọkọ akero tabi ọkọ oju-irin alaja nigbagbogbo lati gba tikẹti o ni lati lọ si ọfiisi tikẹti tabi ibudo gbigba agbara nibiti o ti laini ati duro de akoko rẹ eyi le gba akoko paapaa lakoko awọn wakati ti o ga julọ bayi pẹlu awọn tikẹti ori ayelujara o le fo awọn laini ati ra awọn tikẹti rẹ taara lati kọnputa tabi foonu alagbeka rẹ o dabi rira tikẹti lori ayelujara ṣugbọn dipo gbigba nipasẹ imeeli o ti fipamọ si akọọlẹ rẹ eyi tumọ si pe o le gbe awọn tikẹti rẹ nigbakugba ati nibikibi laisi nini lati rin irin-ajo ti ara si ipo kan pato o le ṣe ni ile ni ibi iṣẹ tabi paapaa lori lọ gbogbo ohun ti o nilo ni asopọ intanẹẹti lilo iṣẹ ori ayelujara yii o le yan iru tikẹti ti o nilo yan iye naa ki o ṣe isanwo lori ayelujara ni kete ti o ti ṣe tiketi naa ti gbe si akọọlẹ rẹ ati ṣetan lati lo nigbati o nilo rẹ eyi fi akoko pamọ ati fun ọ ni irọrun nla ni ṣiṣakoso awọn tikẹti rẹ pẹlupẹlu o ko ni lati ṣe aniyan nipa aabo ti alaye ti ara ẹni ati awọn sisanwo eto ti a lo nipasẹ ẹrọ ori ayelujara wa ni aabo pẹlu awọn igbese aabo lati ṣe iṣeduro aṣiri ti data rẹ ni akojọpọ awọn tikẹti ori ayelujara fun ọ ni irọrun ti fo laini irọrun ti gbigba awọn tikẹti rẹ nigbati o rọrun julọ fun ọ ati alaafia ti ọkan nipa aabo o jẹ ojutu ti o wulo lati jẹ ki o rọrun lati gba awọn tikẹti rẹ ati jẹ ki awọn irin-ajo rẹ ni ito diẹ sii a ni - awọn atunṣe ti 20 50 100 150 200 250 et 500 - awọn atunṣe ti 20 50 100 150 200 ati 250 ireti eyi yoo fun ọ ni oye ti o dara julọ ti awọn tiketi ori ayelujara |
niche theniche jẹ́ ìwé-ìròyìn orí ayélujára ójóójúmọ̀ tí orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ìṣètò ní 20 oṣù kẹrin ọdún 2014 ní ikeja ìpínlẹ̀ èkó theniche tí forúkọsílẹ lábẹ́ àwọn ilé-iṣẹ àti òfin àwọn ọrọ tì 1990 àti pé ó jẹ atẹjáde nípasẹ̀ acclaim communications limited ìtàn theniche jẹ ìwé ìròyìn orí ayélujára tí ó dá nípasẹ̀ àwọn óníṣé ìròyìn nàìjíríà-alàkòsò àti olùdarí / ólóótú ni olórí ikechukwu amaechi eugene onyeji emeka duru àti kehinde okeowo theniche bẹrẹ̀ ìkéde ni 20 oṣù kẹrin ọdún 2014 ní ọdún 2018 àjọ náà ṣètò ipilẹ theniche fún ìdàgbàsókè ìwé ìròyìn ní ilépá àwọn ìpìlẹ̀ wọnyí àwọn atẹjadé kẹta àti kẹrin ní ọdún 2020 àti 2021 kò dúró nítorí ájákáye-àrùn covid-19 ní ọdún 2022 àjọ náà fí babatunde fashola kingsley moghalu anya oko anya christopher kolade remi sonaiya àti tanko yakasai sínú ẹgbẹ́ gbajúmọ èniyàn rẹ ọlá tí á fí pamọ fún àwọn ẹní-kọọkan tí ó sọ ọrọ̀ lórí ìkọ̀wé lọ́dọọdún theniche tàbí ṣé bí àwọn alága ìkọ̀wé lọọdọdún theniche theniche oun ní ọdọọdún ìkọ̀wé gbogbo ọdún làti sọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ilé ajé àti ìjọba tíwáńtíwá ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹ̀sán ọdún 2022 babatunde fashola mínísìítá fún ètò ìṣe àti ilé nàìjíríà jíròrò lórí ìdìbò nàìjíríà 2023 àti ọjọ́ iwájú ìjọba tíwáńtíwà nàìjíríà ní ìkéde 2022 tí ìkọ̀wé lọdọọdún theniche |
media trust media trust jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn aládàáni tó wà ní abuja tó máa ń tẹ ìwé-ìròyìn daily trust weekly trust sunday trust ní èdè gẹ̀ẹ́sì àti ìwé-ìròyìn aminiya ní èdè hausa bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n máa ń ṣàgbéjáde ìròyì ilẹ̀ africa tí wọ́n ń pè ní kilimanjaro ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ilé-iṣẹ́ ìgbéròyìn jáde ní ilẹ̀ nàìjíríà ìtàn nípa rẹ̀ wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ weekly trust ní oṣù kẹta ọdú 1998 àti daily trust ní oṣù kìíní ọdún2001 àwọn ìwé-ìròyìn méjèèjì yìí jẹ́ èyí tó tànkálẹ̀ jù lọ ní apá gúúsù ilẹ̀ nàìjíríà ẹgbẹ́ ìwé-ìròyìn yìí lékè láárin àwọn ìwé-ìròyìn méje tó ń ṣáájú ní ilẹ̀ nàìjíríà nínú ètò ìpolówó ọjà àkóónú ìwé-ìròyìn yìí ní àtẹ̀jáde orí ayélujára àwọn àkóónú inú ìwé-ìròyìn yìí sì jẹ́ títẹ̀ jáde láti ọwọ́ àwọn allafrica àti gamji ilé-iṣẹ́ náà ṣàfihàn àmì-ẹ̀yẹ ti daily trust african of the year láti fi gbóríyìn fún àwọn ọmọ ilẹ̀ africa tó ti kó ipa ribiribi nínú ọ̀rọ̀ ilẹ̀ africa tí wọ́n sì ti ní ipa gidi lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn mìíràn |
naija news nigerian online newspapernaija news jẹ́ ile-ise oni ìwé ìròyìn ẹ̀rọ ayélujára tí nàìjíríà wọ́n dáa sílè ni ọdún 2016 nípa ọgbeni opemipo olawale adeniyi history wọ́n dá naija news sílẹ̀ ní ọdún 2016 pẹ̀lú ati leyin polance media limited ní ọdún 2021 ile-ise yìí kó lọ sí ikoyi ni ìpínlè eko láti tẹsiwaju nínú ìṣe wọn |
elizabeth olsen elizabeth chase olsen tí a bí ní ọjọ́ kẹríndínlógún oṣù kejì ọdún 1989 jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà wọ́n bi ní sherman oaks california olsen ti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe láti ìgbà tí ó ti jẹ́ ọmọ ọdún merin ó kópa nínú fíìmù fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú fíìmù martha marcy may marlene ní ọdún 2011 ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ critics' choice movie award nítorí ipa rẹ̀ nínú fíìmù náà olsen tún padà gba àmì-ẹ̀yẹ bafta rising star award ní new york university lẹ́yìn ọdún méjì olsen gbajúmọ̀ káàkiri àgbáyé fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wanda maximoff / scarlet witch nínu àwọn fíìmù marvel cinematic universe ó wà nínú àwọn fíìmù bi ' 2015 ' 2016 ' 2018 ' 2019 àti doctor strange in the multiverse of madness 2022 pẹ̀lú pẹ̀lú wandavision 2021 |
ìjàpá lọ jẹ àsè ní ilé àdán ìfáàrà ní ìgbà láéláé tí àwọn àròsọ fi yé wa wípé àwọn ẹranko a máa sọ̀rọ̀ bí ènìyàn ìjàpá jẹ́ ẹranko tí ó kún fún ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ púpọ̀ púpọ̀ ní akoko yi itan sọ fun wa wipe ọrẹ timotimo ni ijapa ati àdán ijapa n gbe ilẹ nigbati adan n gbe ori igi kan lẹba ọsa ṣugbon iṣẹlẹ kan ṣẹ ni akoko yii laarin awọn mejeeji ìtàn ni igba iwasẹ ti ijapa ati adan nṣe ọrẹ minu ijapa a maa pe adan si ibi inawo gbogbo ti o ba nse yala isọmọlorukọ iṣile tabi irufẹ inawo yowu ti ko ba maa ṣe ṣugbon o n ka ijapa lara wipe oun kii le lọ si ibi inawo yowu ti adan ba n se nitori wipe ijapa ko le fo debi wipe yoo de ile adan lori igi nigba ti ọrọ yii ka ijapa lara ninu ọgbọn ẹwẹ rẹ o pinnu lati wa nkan ṣe si ohun ti o n dun lọkan ori kuku ba ijapa ṣe nitori wipe ohun ti adan ti n woju eledua fun lati ọjọ to ti pẹ wọle wẹrẹ ọmọbinrin ni iyawo adan ti n bi ṣaaju asiko yii ṣugbon eledumare fi ọmọkunrin lanti ta a lọrẹ ni akoko yii inu adan dun tobẹẹ gẹ nitori naa kuku-kẹkẹ isọmọlorukọ yii kàmọ̀nmọ̀n iroyin ipalẹmọ yii lo ta si ijapa leti ti o fi pinnu wipe bo ṣe gbigbe bo ṣe wiwọ oun o de ile adan lori igi lati wa nibi isọmoloruko naa ijapa ọlọgbọn ẹ̀wẹ́ kuku ri ọgbọn ta si i ohun ti o ṣe ni wipe o lọ wa aṣọ alaari to jọju o wa ranṣe pe adan wipe ki o wa gbe ẹbun ti oun fẹ fun lati fi ba a yọ wipe o bi ọmọkunrin lanti nigbati ijapa gburo wipe adan ti n bọ wa gba ẹbun naa o sọ fun yannibo aya rẹ wipe ki o we oun mọ inu aṣọ naa ni idi eyi nigbati adan gbe aṣọ de ile rẹ lori igi wuya ni ijapa yọ si eleyi jọ adan loju pupọpupọ o si wi fun ijapa wipe oun gba wipe ọlọgbọn ẹwẹ ni nitootọ ijapa jẹ o mu o ranju bọnbọn nibi ase isọmọlorukọ naa odidi ọjọ mẹta gbako ni won fi ṣe ayẹyẹ naa ni igbati ọti tan ti ọka ko si mọ ijapa wa ranti ile o ku bi yoo ti ṣe dele ijapa ro ninu ara rẹ wipe ọgbọn ni oun o tun ta lati ri wipe oun de ile nitori ile koko ni ti agbe ijapa pe adan o ni ọrẹ mi ṣe o ṣe akiyesi wipe a kere pupọ ju awọn ẹranko miran lọ adan da lohun wipe oun naa ti n ro ijapa ni àrùn lo fa o arun ọhun si wa ni idi gbogbo ẹranko awọn ti o ba ti yọ ti wọn ni won n tobi bii erin ẹfọn igala ati bẹẹbẹẹ lọ ni idi eyi adan ati ijapa yoo ba ara wọn yọ arun naa inu adan dun o si imọnran ti ijapa mu wa yii ko tilẹ yiri rẹ wo ti o fi gba a ijapa ree igba ti o wa ni idi rẹ ti o ba fi mu nkan ko si ẹni ti o le fa a yọ kẹrẹ ti adan ti ọwọ bọ idi rẹ ni o fi igba idi rẹ mu ṣikun adan fa ọwọ rẹ yọ ti ni idi ijapa o kigbe titi ṣugbọn ijapa ko ṣi idi rẹ debi pe adan yoo ri ọwọ rẹ yọ pada ijapa ba ṣe oju paiko lo sọ fun adan pe ti ko ba gbe oun pada si ile oun ni isalẹ a jẹ wipe ọwọ adan ge danu nuu bayi ni o di dandan ki adan gbe ijapa pada si ile rẹ ni isalẹ igi lati ile adan ti o wa lori igi |
evangeline lilly nicole evangeline lilly tí a bí ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 1979 jẹ́ òṣèrébìnrin àti òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀ èdè kanada ó gbajúmọ̀ nígbà tí ó kó ipa kate austen nínú eré tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ lost 20042010 òun sì ló jẹ́ kí wọ́n yán fún àmì-ẹ̀yẹ golden globe award for best actress in a drama series lilly ti kópa nínú ọ̀pọ̀lopọ̀ fíìmù bi the hurt locker 2008 real steel 2011 gẹ́gẹ́ bi tauriel nínú àwọn fíìmù the hobbit nínú ' 2013 àti ' 2014 ó kó ipa hope van dyne nínú fíìmù marvel cinematic universe tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ ant-man 2015 lilly tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìwé àwọn ọmọdé tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ the squickerwonkers |
kánádà kánádà |
tessa thompson tessa lynne thompson tí a bí ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹsàn-án ọdún 1983 jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀ èdè amerika ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré pẹ̀lú ilé isé los angeles women's shakespeare nígbà tí ó ń kàwé ní ilé ìwé santa monica college ó wà nínú eré the tempest àti romeo and juliet ipa rẹ̀ nínú eré romeo and julie sì mú kí wọ́n yàn fún àmì-ẹ̀yẹ naacp theatre award ó gbajúmọ̀ nígbà tí ó ṣeré nínú fíìmù tí tina mabry ṣàgbéjáde mississippi damned 2009 àti fíìmù tyler perry tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ for colored girls 2010 |
union bank of nigeria union bank of nigeria plc jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé-ìfowópamọ́ ilẹ̀ nàìjíríà tí olú-ilé-iṣé rẹ̀ wà ní victoria island lagos ó ti ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà láti ọdún 1917 àkópọ̀ union bank jẹ́ ilé-ìfowópamọ́ ńlá tó ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ènìyàn ilé-iṣẹ́ kékeré àti alábọ́dé pẹ̀lú àwon ilé-iṣẹ́ ńlá ní oṣù keje ọdún 2009 wón tò ó pọ̀ sí ipò 556th ìyẹn mọ́ àwọn ilé-ìfowópamọ́ tó tóbi jù lọ ní àgbáyé àti sí ipò kẹrìnlá ìyẹn sára àwọn ilé-ìfowópamọ́ tó tóbi jù lọ ní ilẹ̀ africa títí di ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 2018 gbogbo dúkìá ilé-ìfowópamọ́ náà ń lọ bí i ngn1381 bílíọ́ọ̀nù us 41billion owó tí ó kan àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn nínuh ilé-ìfowópamọ́ náà ń lọ ngn286 bílíọ́ọ̀nù us 851 million ìtàn a lè tọ́ka ìtàn ilé-ìfowópamọ́ yìi sí ọdún 1836 nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ báǹkì ìlú london àti onísòwò ilẹl britani gba ìwé àéhùn ọlọ́lá lahti ọwọ́ wiliam iv láti máa ṣàkóso ètò ìṣòwol báǹkì ní caribbean ẹgbé àwọn olùdókòwò yìí sì ṣèdásílẹ̀ colonial banklátàri òfin tí iléìgbìmọ̀ aṣòfin gbé kalẹl pé àwọn ilé-ìfowópamọ́ le ń ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ káàkiri caribbean àti lẹ́yìn odi colonial bank wá bẹ̀rè iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní ọdún 1917 isé náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú dídá ilé-iṣẹ́ sí ìpínlẹ̀ èkó jos àti port harcourt wọ́n ṣí àwọn ẹ̀ka mìíràn sílẹ̀ ní ọdún 1918 ní ebute metta onitsha ìbàdàn kano àti zaria wọ́n sì tún dá òmítàn sílẹ̀ ní burutu ní ọdún 1921 |
florence kasumba florence kasumba tí a bí ní ọjọ́ kẹrindínlógbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1976 jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀ èdè uganda àti jamini ọ̀pọ̀ mọ́ fún ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bí enikan tí ó ń jẹ́ ayọ̀ nínú fíìmù àwọn fíìmù ilé isé marvel cinematic universe bi ' 2016 black panther 2018 ' 2018 àti 2022 ó tún kó ipa ayò nínú fíìmù disney+ tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ the falcon and the winter soldier 2021 ó gbajúmọ̀ fún ṣíṣe eré nínú àwọn fíìmù jámánì àti dutch ó tún kó ipa gẹ́gẹ́ bi senator acantha nínú wonder woman 2017 shenzi nínú the lion king 2019 àti wicked witch of the east nínú fíìmù nbc tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ emerald city 2017 ìpìlẹ̀ wọ́n bí florence kasumba ní ọjọ́ kẹríndínlógún oṣù kẹwàá ọdún 1976 ní kampala orílẹ̀ èdè uganda wọ́n tọ dàgbà ní essen germany níbi tí ó ti lọ ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé ìwé sẹ́kọ́ńdírì ó padà gba àmì-ẹ̀yẹ ẹ̀kọ́ nínú eré sise orin kíkọ àti ijó jíjó ní fontys university of applied sciences ti tilburg netherlands ó le sọ èdè kasumba german english àti dutch ó ń gbé ní berlin orílẹ̀ èdè germany |
fidelity bank nigeria fidelity bank tí a tún mọ̀ sí fidelity bank plc jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé-ìfowópamọ́ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí olú ilé-iṣé wọn wà ní victoria island lagos ó jẹ́ ilé-ìfowópamọ́ tó ti gbàwé àṣẹ tí central bank of nigeria sì ti fòǹtẹ̀ lù gẹ́gẹ́ b́i báǹkì oníṣòwò ilé-ìfowópamọ́ ti fidelity ti pẹ̀ka láti ibi gegele ó sì ti di ilé-ìfowópamọ́ tó dúró ṣinṣin tó sì ti gbayì láwùjọ ní ọdún 2005 ilé-ìfowópamọ́ yìí gba fsb international bank plc “fsb” àti manny bank plc “manny” láti ṣẹ̀dá ọ̀kan nínú àwọn báǹkì mẹ́wàá tó ga jù lọ ní nàìjíríà ní ọdún 2011 báǹkì náà wà ní ipò keje nínú ààtò àwọn báńkì tó tóbi jù lọ ní nàìjíríà àti ipò karùndínlọ́gbọ̀n nínú ààtò àwọn báǹkì tó tóbi jù lọ ní africa wọ́n tún fi sípò kẹrin ìyẹn lára àwọn báǹkì tó dára jù lọ ní orílè-èdẹ̀ nàìjíríà ìtàn fidelity bank of nigeria forúkọ sílẹ̀ ní ọdún 1987 wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1988 ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òwò kékèèké fidelity bank yí padà láti di ilé-ìfowópamọ́ oníṣòwò ńlá ní ọdún 1999 pẹ̀lú ìgbìyànjú láti dàgbà gẹ́gẹ́ bíi ilé-iṣẹ́ tó ní ìpín ìkọ̀kọ̀ àmọ́ ó di ilé-iṣẹ́ tó nípìín gbangba ní ọdún 1999 bákan náà ọdún náà lorúkọ rẹ̀ sì yí padà sí fidelity bank plc |
polaris bank limited polaris bank limited jẹ́ ọ̀kan lára àwon ilé-ìfowópamọ́ ilẹ̀ nàìjíríà ó gba ìwé-àṣẹ lọ́wọ́ central bank of nigeria èyí tó jẹ́ olùṣàkóso àwọn ilé-ìfowópamọ́ ní orílẹ̀-èdè náà ní oṣù kẹwàá ọdún 2022 strategic capital investment limited scil gba báǹkì yìí láti sọ ọ́ di ohun ìní wọn àwòpọ̀ polaris bank jẹ́ olùpèsè ètò ìṣúná ńlá ní apá ìwọòrùn áfíríkà àti central africa pẹ̀lú olú-ilé-iṣẹ́ ní nàìjíríà títí di oṣù kẹsàn-án ọdún 2010 gbogbo ohun-ìní báǹkì náà ń lọ bíi 39 bílíọ́ọ̀nù ngn 6115 bílíọ́ọ̀nù ìpín àwọn shareholder sì ń lọ bíi us 630 million ngn 984 bilionu ìtàn a lè tọ́pa ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ilé-ìfowópamọ́ náà sí ọdún 1989 nígba ̀ tí prudent bank plc gba ìwé-àṣẹ láti di ilé-iṣẹ́ onípìín gbangba ní ọdún 1990 báǹkì náà gba ìwé-àṣẹ láti máa ṣòwò kékèèké lọ́dún kan náà ó yí orúkọ dà sí prudent merchant bank limited ní ọdún 2006 prudent merchant bank limited parapọ̀ mọ́ báǹkì mẹ́ri mìíràn láti di skye bank plc ní oṣù karún-ún ọdún 2021 báǹkì náà ṣe ìfilọ́lẹ̀ vulte èyí tó jẹ́ pẹpẹ ilé-ìfowópamọ́ náà lórí ẹ̀rọ-ayélujára ilé-ìfowópamọ́ náà ní ìpèsè fún ìṣòwò lórí ẹ̀rọ-ayélujára àti lórí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ ní ọdún 2014 ilé-ìfowópamọ́ náà gba mainstreet bank limited |
adetunji femi fadina adetunji femi fadina ni alága ẹgbẹ́ tourism practitioners of nigeria atpn èyí tó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ nàìjíríà òun sì ni adarí àgbà ti ilé-iṣẹ́ jethro tours and awori initiative ó sì tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ trade promotion board fún ẹ̀ka tó ń rí sí ètò ìṣòwò àti ilé-iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ èkó ètò ẹ̀kọ́ ilé-ìwé loyola college ní ìbàdàn ní ó ti parí ẹ̀kọ́ girama ní ọdún 1980 ó sì tẹ̀síwájú láti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ business administration and management ní samford university láti ọdún 1981 wọ ọdún 1984 iṣé rẹ̀ adetunji ni olùdásílẹ̀ awori tourism consulting firm àti ààrẹ association of tourism practitioners in nigeria èyí tó jẹ́ ẹgbẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìrìn-àjò àti ìgbéga àti ìdúróṣinṣin àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìrìn-àjò òun náà sì ni olùdarí àgbà àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣé dinat consulting inc adetunji tí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí nínú iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìrìn-àjò èyí sì hànde nínú ìṣèdásílẹ̀ ẹgbẹ́ kan tó sọ ní jethro tours institute ní ọdún 2019 ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àṣà àti ìrìn-àjò ní ìpínlẹ̀ ògùn pe adetunji láti wá sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọdọọdún wọn láti ṣègbélárúgẹ àṣà àti ètò ìrìn-àjò tó máa ń wáyé ní ìlú abẹ́òkúta |
ajégúnlẹ̀ ajégúnlẹ̀ tí eọ́n tún ń dàpè ní aj city or simply aj jẹ́ agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ èkó tí ó wà ní abẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ajérọ̀mí ifẹ́lódùn ajégúnlẹ̀ pààlà pẹ̀lú ibùdó etíkun àpápá wharf àti tincan tí wọ́n jẹ́ ibùdó ìkẹ́rù wọlé lórí omi tí ó tòní jùlọ ní ìpínlẹ̀ èkó tí oríṣiríṣi nkan ti wọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà iye awọn plùgbé ajégúnlẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀taléláàádọ́ta ènìyàn níbi tí a ti rí gbogbo ẹ̀yà orílẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn tí wọ́n jẹ́ olùgbé tí wọ́n pọ̀ jùlọ ní agbègbè náà ni àwọn ẹ̀yà yorùbá tí wọ́n jẹ́ ijaw àti ìlàjẹ àwọn lààmì-laaka ènìyàn ibẹ̀ oríṣiríṣi àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ lààmì-laaka ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ati gbogbo agbáyé ni wọ́n tara ajégúnlẹ̀ dìde lára wọn ni a ti rí agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀rí fún orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ó tún ti jẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá un orílẹ̀-èdè nàìjíríà rí samson siasia bákan náà ni a tún ti rí agbábọ́ọ̀lù atamátàsé tí ó ń gbà bọ́ọ̀lù lọ́wọ́ iwájú fún ikọ̀ manchester united ìyẹn odion ighalo ibẹ̀ náà ni a tún ti rí agbábọ́ọ̀lù lọ́wọ́ ẹ̀yìn fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí ìyẹn taribo west bẹ́ẹ̀ náà ni a rí chinwendu ihezuo tí ó gbà bọ́ọ̀lù jeun nínú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù obìnrin ilẹ̀ nàìjíríà a tún rí emmanuel amuneke tí òun náà jẹ́ agbábọ́ọ̀lù fún orílẹ̀-èdè nàìjíríà tẹ́lẹ̀ lára wọn náà ni ìlúmọ̀ọ́ká olórin tàkasúfè daddy showkey |
ẹ̀yà awori awori jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà àwọn ọmọ yorùbá tí ń sọ èdè kan pàtó èyí tí í ṣe èdè yorùbá ìwọ̀n agbègbè ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àwọn ẹ̀yà àwórì wà ní ìpínlẹ̀ ògùn àti ìpínlẹ̀ èkó ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn ìlú bíi ikorodu epe badagry ota ado-odo isheri igbesa agbara ilobi àti tigbo jẹ́ ibùgbé àwọn awori láàárín ìpínlè ògùn tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1976 ní orílè-èdè nàìjíríà àwọn ará awori ní ìtàn-àkọọ́lẹ̀ pípẹ́ nípa níní ibùgbé sí àárín èkó èyí tó bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìjọba amúnisìn àwọn ni wọ́n dá ìlú èkó sílẹ̀ wọ́n jẹ́ pẹjapẹja àti oníṣòwò ó sì fìdí múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òwò tí wọ́n ń ṣe ní apá ìwọòrùn áfíríkà ìtàn orísun ìtàn náà ni pé olófin àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kúrò ní ààfin ọba odùduwà tó jẹ́ olùṣẹ̀dásílẹ̀ ilẹ̀ yorùbá ní ilé-ifẹ̀ wọ́n sì ṣí lọ síhà gúúsù létí odò kan odùduwà ti fún olófin ní àwo kan tí wọ́n mọ ó ní kí ó gbé e sórí omi kí ó tẹ̀lé e títí tí ó fi máa rì sínú odò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tí wọ́n kúrò ní ilé-ifẹ̀ àwo náà dúró lójijì sí agbègbè olókèméjì nítòsí abeokuta tòde òní lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́tàdínlógún ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ ó sì dúró sí òkè-ata fún ọjọ́ mẹ́tàdínlógún mìíràn ní ìparí ọjọ́ mẹ́tàdínlógún àwo náà tún bẹ̀rẹ̀ síí lọ ṣàdédé ni ó dúró sí ìhà gúúsù ti abẹ́òkuta lónìí níbi tó ti dúró fún ọjọ́ mẹ́t̀dínlógún mìíràn níbí yìí ni àwọn ọmọ ọlọ́fin kan pinnu láti dúró tí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ osho aro-bi-ologbo-egan sì jẹ́ olórí àwo náà tẹ̀síwájú sí ìsàlẹ̀ ó sì tún dúró ní isheri ọlọ́fin bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn ìletò kan sílẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn náà sì béèrè pé níbo ni àwo náà wà ó sì dáhùn pé àwo ti rì báyìí ni wọ́n ṣẹ̀dá orúkọ wọn awori ọlọ́fin ní ìyàwó méjì orúkọ wọn sì ni akesan àti ajaiye akesan bímọ ọkùnrin méjì ìyẹn ogunneru àti ogunbiyi tí ajaiye sì yàgàn lẹ́yìn tí wọ́n tẹ̀dó sí ìlú ìṣerì olófin lọ wádìí ọ̀rọ̀-onífẹ̀ẹ́ ifá níbi tí wọ́n ti ní kí wọ́n lọ síbi tí omi iyọ̀ wà wọ́n si ṣí kúrò ní iṣeri tí wọ́n wá lọ sí iddo níbi tí wọ́n sì gbé ajaiye bí ọmọ mẹ́jọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn tí wọ́n sì máa dàgbà di idejo òde-òní ó fún wọn ní ilẹ̀ láti máa ṣe oko àwọn idejo náà ni aromire ojora onikoyi oniru oluwa oloto olumegbon àti elegushi ogunneru ló padà gorí oyè lẹ́yìn ọlọ́fin tí ó sì di ọlọ́fin isheri nígbà tí ogunbiyi sì lọ tẹ àwọn ìlú mìíràn dó ní awori ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ orò àti oree egúngún elegba ìgunukó opa osugbo àti gẹ̀lẹ̀dé wà lára àwọn ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ tí wọ́n máa ń ní ní ìlú awori wọ́n sì máa ń ṣayẹyẹ àwọn ọdún ẹ̀sìn mìíràn bíi ẹ̀sìn musulumi àti ọdún kérésìmesì fún àwọn kìrìsìtẹ́ẹ́nì èyí sì máa ń mú kí àwọn ọmọ-ìlú tó wà nílẹ̀ òkèèrè padà wálé láti wá bá wọn ṣàjọyọ̀ |
koko komégne koko komégné jẹ ayaworan ti o kale si ilu douala ati olupolowo ti aaye aworan asiko ni ilu kamẹrika igbesi aye ati iṣẹ abi koko komégné ni odun 1950 ni batoufam ni ọdun 1956 o lọ si yaoundé nibiti o ti lọ si ile-iwe ati pe o bẹrẹ iyaworan ati gbigbọ gbogbo awọn orin ni 1960-62 o ṣe agbejade ere akọkọ rẹ le boxeur ati ni 1965 lẹhin ọpọlọpọ ipenija o gbe lọ si douala nibiti o ti pade jean sabatier oluyaworan magbowo ti yoo fa u lati kun ni 1966 komégné ṣii atelier akọkọ rẹ gẹgẹbi ikẹkọ o bẹrẹ si tun ṣe awọn iṣẹ-ọnà nipasẹ awọn oluyaworan pataki van gogh picasso bbl ati fun igbesi aye o ṣe awọn ipolowo ipolongo ni ọdun 1968 o jawe olu bori ninu idije iyaworan biscuits berlin ati pe o ṣiṣẹ fun ọdun kan lori ọkọ oju-omi kekere kan ti o lọ kiri awọn eti okun ti arin gbungbun afrika ni 1971 o ṣe alabapin si iṣafihan ẹgbẹ akọkọ rẹ ti a ṣeto ni douala nipasẹ igbimo française pour la formation des cadres ni ọdun 1972 o ṣi igi kan lẹgbẹẹ ile rẹ nibiti o ti pe awọn akọrin ati nibiti o ti nṣere bi akọrin ati akọrin ni igba diẹ o di akọrin ti ẹgbẹ orin agbara awon alawo dudu ni ọdun 1986 o pinnu lati ṣojumọ lori kikun o lọ si agbegbe ti o dakẹ ati pe o ṣe igbeyawo ni ọdun 1990 o ṣe igbeyawo fun igba keji ati pe o ni ọmọbirin kan fun ẹniti o ṣe iyasọtọ ifihan ise re ti ape ni “evanescence” ni ọdun 2008 ni espace doual'art lẹhin ikọsilẹ miiran o ṣe igbeyawo fun igba kẹta o si ni ọmọ mẹrin ni ọdun 1997 o jẹ ipalara ijamba kan ati pe o wa ni ile-iwosan fun oṣu mẹrin ni 2000 o ni lati lọ kuro ni atelier rẹ ni agbegbe bonadibong ni douala ati pe o lọ si ccc agbegbe lẹhin ifowosi awọn aworan rẹ komégné gaston koko décor gaston komé o yan lati maa fowosi awọn aworan rẹ pẹlu orukọ koko komégné apapo orukọ baba rẹ kouamo ati orukọ rẹ komégné ninu iṣẹ ti ara ẹni o ṣojumọ lori orin ijó awọn panṣaga osi igbesi aye alẹ ati awọn iboju iparada ni 1974 o ṣe agbejade aworan ti fiimu pousse pousse nipasẹ daniel kamga fiimu akọkọ ti ilu kamẹrika ati ni ọdun 1976 o ni iṣafihan adashe akọkọ rẹ ni quartier latin ẹgbẹ ile ounjẹ kan ni douala ni ọdun 1979 o kopa ninu idije akọkọ fun awọn odo oluyaworan ọmọ ilu kamẹroon ni odun 2005 akọkọ àtúnse ti awọn biennale of douala devotes a oriyin si koko komégné ati ni 2006 doual'art se agbateru awọn jakejado adashe itaja koko komégne 40 ans de peinture ti didier schaub gbe jade ni 1985 o ṣe ọṣọ ogba black et white ni limbe ati ile itura arcade ni douala ni 1986 cabaret le vieux négre ni douala ati ni 1987 ile itura mountain ni buéa ati ile-iṣẹ ile-ẹkọ giga ni dschang ni 1989 ile itura hilton ni yaoundé ṣe ọṣọ awọn yara rẹ pẹlu awọn aworan olokuta nipasẹ koko komégné ni 1993 o ṣe ọṣọ phaco club international ati ọgbà ounjẹ parfait ni douala ni 1994 ile itura central ni yaoundé ni 1995 ile itura méridien ni douala fun u ni ọpọlọpọ awọn frescos 11 eyiti yoo jẹ idamu lẹhin ti ile itura naa yipada iṣakoso ni 2002 o ṣe awọn frescos fun ile titun ti ile-iṣẹ idaniloju la citoyenne ni douala ati ni 2003 ile itura sofitel mont fébé ni yaoundé ṣe ọṣọ awọn yara 90 rẹ pẹlu awọn lithographs nipasẹ komégné ni odun 1992 o ṣe alabapin ninu art venture idanileko ti a ṣeto nipasẹ aṣa aṣa doual'art eyiti o ṣe agbejade fresco triptych 45m gigun nipasẹ 15m giga ni plexiglas ti a fi sori ẹrọ ni dakar square ni douala ni 1993 o jẹ oludari iṣẹ ọna ti doual'art pop '93 idanileko ti a ṣeto nipasẹ doual'art ni agbegbe madagascar ni douala ninu eyiti awọn oṣere 25 ṣe awọn frescos lori awọn ọja iṣura ti agbala ile kan ni ọdun kanna o ṣe alabapin ni cadavres exquis ni mbappé leppé stadium ni douala ati pe o jẹ ọmọ igbimọ ti festival national des arts et de la culture ni 1997 o ṣe alabapin ninu le kwatt idanileko ti a ṣeto nipasẹ doual'art ni agbegbe makepe petit-pays ni douala ati ni 1998 ni entr'artistes curated nipasẹ mariela borello ni doual'art ni oṣu kẹta 2007 o ṣe alabapin ninu ars et urbis international idanileko ati ni oṣu kejila ni sud-salon urbain de douala koko komégné ṣe igbega aworan ati awọn ayaworan ni ilu kamẹroon o ṣe alabapin si awọn eto redio 500 awọn eto tv 100 ati awọn ifọrọwanilẹnuwo 500 lori awọn iwe iroyin ati awọn iwe iroyin ni 1979 o ṣẹda ẹgbẹ akọkọ ti awọn oṣere ti cameroon cercle maduta meduta tumọ si awọn aworan ni ede douala pẹlu awọn oṣere viking kanganyam jean-guy atakoua ati samuel abélé cercle maduta tilekun ni 1983 nigbati koko komégné ṣe awari pẹlu awọn oṣere miiran caplit - cercle des artites plasticiens du littoral ni 1980 ha ifihan ni menuiserie etd mucam meubles a aga itaja ni 1981 o ni iṣafihan ifẹhinti akọkọ rẹ 1976-1982 ni ile-iṣẹ aṣa amẹrika ati ni 1982 ni ile-iṣẹ aṣa faranse ni yaoundé o jẹ ọmọ ẹgbẹ ti o ṣẹda ni ọdun 1994 ti ẹgbẹ aṣa ti kheops club eyiti o ṣajọpọ awọn oṣere cemroonian mẹwa pẹlu ero ti igbega iṣẹ ọna wiwo ni ilu kamẹrika ni 1995 o jẹ oludari iṣẹ ọna ti idanileko upemba ni 1995 o ṣe afihan awọn oṣere ọdọ joël mpah dooh blaise bang salifou lindou hervé youmbi ati hervé yamguen ninu ifihan tele miso ni mam gallery ni douala ni 2001 o jẹ olutọju ti ẹgbẹ fihan yann co ni atelier viking ati ti squatt'art idanileko ọsẹ kan ati ifihan pẹlu awọn oṣere 22 ti o ṣii afẹfẹ ni agbegbe bali ni douala ni 2002 o kopa ninu squatt'art ii ni adugbo deïdo ni douala o tun jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ ti o ṣẹda ti aaye aworan ti o nṣiṣẹ olorin-ṣiṣe art wash |
dotun popoola dotun popoola a bi ni ọdun 1981 ni ilu eko jẹ olorin ọmọ orilẹede naijiria ti ode oni ti o ṣe amọja ni fifin irin amuṣiṣẹpọ o ṣẹda awọn ege iṣẹ ọna lati awọn irin alokuirin ti a sọnù awọn iṣẹ rẹ ni idojukọ lori yiyi idọti pada si awọn iṣura idoti si awọn iyùn ati egbin si ọrọ nipa sisọ awọn egbin ti o halẹ si ilolupo eda abemi ibẹrẹ igbesi aye dotun kọ ẹkọ kikun ati iṣẹ ọna gbogbogbo ni auchi polytechnic auchi ipinle edo nibiti o ti gba iwe-ẹkọ giga orilẹ-ede ni kikun ati aworan gbogbogbo ni ọdun 2004 lẹhinna o lọ si ile-ẹkọ giga obafemi awolowo nibiti o ti gba oye akọkọ ati keji ni imọ-jinlẹ ati iṣẹ-iṣe pẹlu amọja ni ere ati aworan lẹsẹsẹ dotun jẹ olorin olugbe ni lopez studio ni lemmon south dakota o si rin irin-ajo laarin amẹrika ati naijiria lati kun awọn aworan ti a fun ni aṣẹ o jẹ olutọju ni national gallery of art awọn ifihan awọn iṣẹ ati awọn ẹbun popoola ṣiṣẹ ni akọkọ pẹlu irin alokuirin nibiti ṣiṣẹda awọn fọọmu ẹranko jẹ ọna ayanfẹ rẹ lati lo alabọde diẹ ninu awọn iṣẹ rẹ ni a ṣe afihan ni art x ni ilu eko o si ní a adashe aranse ti a npe ni irin ajo ajo ni ibuwọlu beyond art gallery lagos ibi ti o ti gbekalẹ ni ayika 24 irin iṣẹ rẹ |
yetunde ayeni-babaeko yetunde ayeni-babaeko ojoibi 1978 je oluyaworan omo naijiria igbesi aye yetunde ayeni-babaeko ni a bi ni enugu agbègbè apáìlàoòrùn nàìjíríà ni ọdun 1978 bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ nàìjíríà ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ará jámánì o gbe lọ si jamani bi ọmọde lọ si ile-iwe giga nibẹ o si pari iṣẹ ikẹkọ fọto yiya ni studio be ni greven ni 2005 o pada si nàìjíríà ni 2007 o ṣii ile-iṣere tirẹ kamẹra studios ti o wa ni ikeja ifihan ayeni-babaeko ti odun 2014 ni a pe ni 'eko moves' ni ifowosowopo pẹlu ajo awon olosere ti nàìjíríà ṣe afihan awọn onijo ni awọn aaye gbangba ni ilu eko ifihan 2019 rẹ ni 'white ebony' ṣe afihan ipo ti awọn eniyan ti o ni albinism |
trade union congress àjọ àwọn òṣìṣẹ́ àgbà trade union congress of nigeria tuc jẹ́ ọ̀kan lára àjọ national trade union federation lórílẹ̀-nigeria tí ó dálé ṣíṣojú àwọn òṣìṣẹ́ àgbà |
national trade union federation national trade union federation jẹ́ àgbájọpọ̀ àwọn àjọ ayédáadé àti àjà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ó fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ni ó ní ajọ̀ yìí káàkiri ní orílẹ̀-èdè wọn tí wọ́n sì ní ilé-iṣẹ́ àjọ yìí káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni ju ilé-isé kan lọ fún àjọ yìí làwọn àgbègbè mìíràn pàápàá jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè apá àríwá europe wọ́n ni ilé-isé àjọ yìí fún àwọn oníṣẹ́-ọwọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún ní i fún àwọn alákọ̀wé òṣìṣẹ́ |
george edozie george edozie ojoibi 1972 je oluyaworan omo naijiria ngbe ni lagos nigeria igbesi aye ibẹrẹ ati ẹkọ won bi george edozie ni 11 oṣu karun ọdun 1972 o lọ si ile-iwe alakọbẹrẹ university ni nsukka ile-iwe iranti iranti washington onitsha edozie kawe fine applied arts ni yunifasiti ti benin ni ilu benin nibi ti o ti kọ ẹkọ ni kikun ti o si gba oye ba ni ọdun 1996 iṣẹ-ṣiṣe george edozie ti ṣe afihan pupọ ni awọn ifihan ẹgbẹ ni nigeria ati ni okeere diẹ ninu wọn pẹlu awọn olorin egbeda mẹfa ni national museum onikan lagos 2002 iwadi ni ile-iṣẹ aṣa faranse ikoyi lagos 2004 pẹlu oju eniyan ni ile-ẹkọ giga pan-african lagos 2006 ati a kaleidoscope of nigerian aso ibile ni abuja 2009 o ti lo si awon iworon pupo peelu awan egbe re ti won jon sise kan no bi awon ebenezer akinola olusegun adejumo peelu gerald chuckwuma ati bee bee lo |
dele jegede dele jegede ti a ṣe ni aṣa bi dele jegede jẹ oluyaworan ara ilu naijiria-amẹrika akoitan aworan alaworan alabojuto alariwisi aworan alabojuto iṣẹ ọna ati olukọ jegede jẹ olukọni post-doctoral agba ni ile-ẹkọ smithsonian ni washington dc 1995 o kọ ni awan of ile iwe ni spelman college atlanta bi alejo fulbright scholar 1987-1988 nigbati o ṣe apejuwe ifihan art nipa metamorphosis akojọ si ni kelly ati stanley's awọn olorin naijiria a tani tani iwe-akọọlẹ jegede jẹ ọjọgbọn ati alaga ti ẹka ti iṣẹ ọna ile-ẹkọ giga ti ipinle indiana terre haute 2002-2005 ati ọjọgbọn ti iṣẹ ọna ni ile-ẹkọ giga miami ni oxford ohio 2005-2010 o feyinti bi ojogbon emeritus ni may 2015 jegede jẹ olugba ti aami eye afirika iyatọ ti ile-ẹkọ giga ti texas lọwọlọwọ o jẹ alaga igbimọ igbimọ ti ẹgbẹ cartoonists ti nigeria cartan igbesi aye ibẹrẹ ati ẹkọ won bi dele jegede ni ikere-ekiti ekiti state nigeria ni odun 1945 won lo si iwe gigan ton ti gba degree akoko ni fine arts ti won foju mo painting late ahmadu bello university zaria nigiria ni 1973 lati 1979 titi de 1983 won ko art history ni odo oga won to jeh roy sieber ni indiana university bloomington indiana ton ti gba degree ikeji to je ma ati phd nko ti wan fi je eyan pataki ni ise ti won se ni indiana university ni 1983 to je trends in contemporary nigerian art to foju mo bruce onobrakpeya ati twins seven seven oni akoko ni nigeria comtemporary art iṣẹ-ṣiṣe jegede bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ amọṣẹ́dunjú rẹ̀ ní nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ayàwòrán àti ayàwòrán ninu e ni josy ajiboye miran cartoons ti o fojusi nipataki lori awujo eya jegede lo rẹ cartoons lati ọrọìwòye lori awọn excesses ti awọn anfaani ati ki o fa ifojusi si awujo ati oselu awon oran ni apapọ adéronke adesanya òpìtàn iṣẹ́ ọnà àti ọ̀mọ̀wé nípa iṣẹ́ ọnà ìgbàlódé ti áfíríkà ka àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ jegede sí gẹ́gẹ́ bí “àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ skeleton orílẹ̀-èdè lati 1974 si 1977 o jẹ olootu aworan ni daily times ti nigeria ojojumọ ti o ni ipa julọ ni nigeria jegede tẹsiwaju lati ṣe atẹjade awọn aworan efe osẹ ni sunday times atẹjade arabinrin kan ti daily times daradara ni ipari awọn ọdun 1970 nigbati o lọ kuro fun awọn ikẹkọ mewa ni ile-ẹkọ giga indiana ni igba diẹ lẹhin ti o pada si naijiria ni ọdun 1983 o tun bẹrẹ sikirinikiri apanilẹrin ọsẹ rẹ kole omole eyiti o ṣe afihan ọmọkunrin odun maarun kan ti o ṣaju nipasẹ ẹniti jegede gba awọn jabs arekereke ni ijọba ologun kjell knudde sọ ogún jegede ati ipa lori ere ere lorilẹ-ede naijiria fun bi olorin ṣe n lo awọn aworan alaworan lati ṣofintoto awọn ijọba ijọba apanilẹṣẹ ati ibajẹ ni orilẹ-ede rẹ ni ọdun 1977 o darapọ mọ olukọ ti ile-iṣẹ fun awọn ijinlẹ aṣa ti ile-ẹkọ giga ti ilu eko ati ṣeto awọn iṣe aṣa ni ibamu pẹlu agbaye keji ati festival festival of arts and culture festac 77 lara awon akegbe re ni centre for cultural studies ti university of lagos ni bode osanyin to je omo leyin bertolt brecht to si je agbejoro tiata gbogbo bakan naa ni joy nwosu akin euba ati lazarus ekwueme wa awọn ọmọ orilẹede naijiria to ṣe pataki julọ ni aaye orin ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní yunifásítì ti èkó gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́gbẹ́ ìwádìí ọ̀dọ́ ní 1977 ó sì kúrò ní 1992 gẹ́gẹ́ bí olùdarí ilé-iṣẹ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àṣà o ṣe lọwọ kii ṣe bi ọmọ ile-iwe nikan ṣugbọn tun bi oluyaworan pẹlu ara ti o yapa lati oriṣi awujọ ti o jẹ agba o ṣe afihan satire sinu awọn aworan rẹ o si ṣojukọ si awọn akori ti agbewọle awujọ ati ti iṣelu gẹgẹbi ninu ifihan 1991 rẹ lori ilu eko olu-ilu aṣa ati owo ti nigeria ni ọdun 1989 wọn yan an gẹgẹ bi ààrẹ society of nigerian artists sna ni arọpo solomon wangboje ẹni ti o jẹ ọmọ orilẹede naijiria akọkọ ti o gba oye oye oye oye nipa iṣẹ ọna ni ọdun mẹta ti jegede gẹgẹ bi aarẹ jegede ni ifipamo iwe adehun ofin fun sna ṣe agbekalẹ eto ijọba tiwantiwa nipa ṣiṣẹda awọn ipin ipinlẹ ṣe apejuwe ifihan pataki kan “awọn aworan ti orilẹ-ede naijiria” pẹlu iwe atokọ ti o tẹle ti akọle kanna o si ṣe itọsọna ipolongo naa fun idasile national gallery of art ni 1993 jegede gba iṣẹ iṣẹ lati indiana state university terre haute o si tun gbe lọ sibẹ pẹlu omo ati yawo re o ti ni idagbasoke ati kọ awọn iṣẹ ikẹkọ ni aworan ile iṣere ati itan-akọọlẹ aworan jegede jẹwọ pupọ bi ọkan ninu ẹgbẹ kan ti awọn ọmọ ile-iwe giga afirika ti o ti tẹsiwaju lati ṣe apẹrẹ itọsọna aaye nipasẹ iwadii imotuntun ti ọmọ ile-iwe wọn ati awọn ilepa curatorial atako rẹ ti o lagbara ti gbigba jean pigozzi eyiti o jẹ apejuwe bi gbigba ti o tobi julọ ni agbaye ti aworan ile afirika ti ode oni ti fa ibawi didasilẹ lati ọdọ thomas mcevilley ẹniti o gbagbọ pe ibawi jegede ko ni igbẹkẹle nitori pe o ti lo akoko pupọ pupọ kuro ni afirika lọ́wọ́lọ́wọ́ elizabeth harney sọ pé ipò mcevilley jẹ́ ojú ìwòye pàtàkì nípa ẹni tí ó yẹ kí ó sọ̀rọ̀ fún nínú àríwísí iṣẹ́ jegede niyi osundare rí jegede gẹ́gẹ́ bí “… ati aficionado ọrọ-ọrọ ti a tọju nipasẹ aṣa ti o ni itara oniruuru ati aṣa ti ukere ni iṣaaju-ominira awọn ọjọ pentecostal ṣaaju ti o ti ni lati awọn ọdun ibẹrẹ gbogbo ohun ti o nilo lati jẹ oṣere lapapọ” ni odun 2017 jegede je okan lara awon araalu ti ogoga ti ilu ikere-ekiti oba adejimi adu gbe wonu hall of fame ikere ni ọdun 2018 jegede ti wọ inu society of nigerian artists hall of fame ọkan ninu ẹgbẹ kan ti awọn oṣere naijiria 20 pẹlu ben enwonwu yusuf grillo ati demas nwoko ti a fun ni ọla ni ikede ọmọbirin naa awọn akojọpọ gbangba iṣẹ ọna jegede wa ni ifihan ni ọpọlọpọ awọn akojọpọ gbangba ati ikọkọ ni nigeria ati amẹrika awọn atẹjade awọn atẹjade jegede pẹlu |
folashodun adebisi shonubi folashodun adebisi shonubi tí wọ́n bí lọ́jọ́ keje oṣù kẹta ọdún 1962 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nigeria àti gómìnà-fìdíhẹ ilé-ìfowópamọ́-àgbà the central bank of nigeria tí ààrẹ bọlá ahmed tinubu yàn lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹfà ọdún 2023 láti rọ́pò gómìnà-àná ilé-ìfowópamọ́-àgbà godwin emefiele tí wọn dá dúró lẹ́nu iṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nítorí àwọn ẹsùn àwọn ìwà àjẹbánu kan |
eewo ninu awon igbagbo yoruba èwọ̀ ní ilẹ̀ yorùbá èwọ̀ jẹ́ ohun tí àwọn ènìyan àwùjọ kan gbà gẹ́gẹ́ bí ìwà ìdọ̀tí ìwà ìtìjú ìwà ẹ̀gbin tí a kò gbọdọ̀ ṣe láarín àwùjọ lára rẹ̀ ni jijoko sori odó awọn eniyan maa n lo odó lati pese diẹ ninu awọn ounjẹ ti wọn fẹ julọ gẹgẹbi iyán fufu ati bẹbẹ lọ ikilọ pataki kan lẹhinna fun wa lati ma joko lori odó eyi jẹ lilo adaṣe bi ọna ti imototo nítorí náà wọ́n ń lò ó gẹ́gẹ́ bí èèwọ̀ láti kó ìbẹ̀rù sínú ọkàn àwọn ènìyàn pipa igun ara yii ko wọpọ ni ọpọlọpọ awọn aaye ikilọ pataki kan wa pe ẹiyẹ yii ti o jẹun lori awọn ẹranko ti o ku ko yẹ ki o pa o ti wa ni wi pe enikeni ti o ba pa igo yoo ku ti won ba se bee gbígbé àkàbà lé èjìká ní àwọn ibì kan ní ilẹ̀ yorùbá gbígbé àkàbà igi lé èjìká dúró fún pósí nítorí náà kí ìwà ibi má baà borí ó jẹ́ èèwọ̀ láti gbé àkàbà kan gẹ́gẹ́ bí àwọn alágbàṣe tí wọ́n ń gbé pósí lé èjìká wọn nígbà ìsìnkú gbigba òjò pẹlu ọwo ni pataki julọ ni a kilo fun awọn ọmọde lati ma gba omi òjò nipa titan owo wọn ni jijo kódà wọ́n tún máa ń sọ pé ààrá lè lù èèyàn bó bá ṣe bẹ́ẹ̀ eyi ni lilo gangan bi igbesẹ kan si imototo ti ara ẹni òrò sisọ lakoko yiyọ awọn iyẹ ẹyẹ adie awọn iye ara ẹiyẹ nigbati o ti yọ kuro lẹhin pipa ni a sọ pe o pọ si ti o ba tẹsiwaju lati sọrọ lakoko yiyọ kuro awọn agbalagba rii daju pe awọn ọmọde pa ẹnu wọn mọ nigba ti wọn ṣe eyi jẹ ipilẹ lati mu iyara ati ṣiṣe lakoko ti o wa lilu ọmọ akọ pẹlu ìgbálẹ eyi jẹ eewọ ti o wọpọ wọ́n ní tí ẹ bá fi ìgbálẹ lu ọmọ akọ ẹ̀yà ara ìbálòpọ̀ yóò pòórá eyi jẹ apẹrẹ ti a lo lati daabobo ọmọ naa lọwọ ilokulo ti ara ṣugbọn kilode ti o kan ọmọ ọkunrin tilẹ aboyun ti nrin ni ọjọ ti oorun== o tun jẹ eewọ fun alaboyun lati ma rin kiri ni oorun gbigbona igbagbo awon yoruba ni awon esu maa n rin kiri ni asiko yii wọ́n gbà pé ọmọ tí kò tíì bí tàbí ìyá náà lè gba àwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyí eyi tun lo bi ọna aabo fun aboyun njẹ gbogbo wa ko nilo itanna diẹ lati oorun nigbati o ba ri oyà ni ọsan ko jẹ ami ti o dara lati ri oyà eran igbo ni ọjọ ìgbàgbọ́ ni pé wàhálà tàbí ibi ń bẹ lọ́dọ̀ ìbátan ẹni tí ó rí ẹranko yìí ní ọ̀sán nigbati aja/ologbo ba kigbe a ri bi ohun buburu fun aja tabi ologbo obo lati kigbe wọn gbagbọ pe wọn sunmọ ẹmi nitori naa nigbati wọn ba sunkun o fihan pe iku wa ni kiakia si ibatan ti eni awọn eniyan gbagbọ pe ni kete ti a ba pa ẹranko yii ibi naa yoo yago fun nígbà tí ọba bá wo adé rẹ̀ èèwọ̀ ni fún ọba tí ń ṣàkóso láti wo adé tirẹ̀ eyi ni idi ti awọn ọba ko fi yọ awọn ade wọn kuro nipa yiyi pada eyi jẹ lẹta kan si iku gẹgẹbi awọn eniyan ti gbagbọ |
àtòjọ àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ èkó èyí ni àtòjọ àwọn gómìnà àti adarí ológun tí ó ti dárí ìpínlè ẹ̀kọ́ láti ìgbà tí wọ́n ti da kalẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tàdínlógbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 1967 |
bernice oasis outreach bernice oasis outreach je iṣẹ iranti ti o mọ ipa lati siṣẹ fun alaini ati lati yipada awọn ọgbọn awọn aye siwaju ninu awọn ilu ti o gbajumo ifihan wa ni lati gba ifẹ ipilẹ ati awọn ohun ti o nilo fun awọn ti o wọ ifiṣọra laaye ni odo lẹhinna ni awọn ipa rẹ ati awọn ọdọ wa si awọn wa ni opin awa ni wa ti wọle si eyikeyi miiran ni ifẹ lati gba ifẹ ati ifiṣẹ laarin awọn ti o wọ ipa ti won si aye ti o gbajumo ni ijọba ifihan wa bernice oasis outreach ni ipilẹ awọn ohun ti o nilo fun awọn alaini ti o nilo ni ifiṣọra laaye awa gbagbọ pe ifẹ ni iṣẹwo alaisan ati gbogbo eniyan ninu iwadi awọn ifiṣẹyan wọle ko nilo lati kọja ifẹ ati ifiṣẹyan lati siṣẹ fun iṣẹwo wa a si gba ifẹ ati awọn ohun ti o nilo fun awọn ti o wọ ipa ti o gbajumo ati ti a dara julọ lori aye gbajumo njẹ a ṣe nikan si oriṣiriṣi ohun ti a ti gbe si awọn ifẹ funrare ti bernice oasis outreach ni asefihan fun awọn ilu ti o gbajumo awa gbagbọ pe ifẹ ni iṣẹwo alaisan ati gbogbo eniyan ninu iwadi awọn ifiṣẹyan wọle ko nilo lati kọja ifẹ ati ifiṣẹyan lati siṣẹ fun iṣẹwo wa a si gba ifẹ ati awọn ohun ti o nilo fun awọn ti o wọ ipa ti o gbajumo ati ti a dara julọ lori aye gbajumo |
bernice akinwande bernice akinwande ni olugbeji alagbeka ti o dara julọ ti o dun lati gba ifẹ ni ifiṣẹyan rẹ ni ifiṣẹyan rẹ ti o dara julọ ati lati ifiṣẹyan o ti da lori aye ni odo ti o mu ifẹjọmọluwabi awọn ọmọde rẹ si ona ifẹ pataki ti o dara julọ ifẹjọmọluwabi bernice ati lati ṣe ifẹjọmọluwabi ati lati ro ṣe afẹfẹ ni awọn eniyan miiran se iranlọwọ kan fun eyikeyi agbara-oorun lati ṣe alagbeka bernice ni awọn ewu idaduro ti o dara julọ ti o dara julọ ti o ba awọn ọmọde rẹ si ifiṣẹ ati lati ifiṣẹyan pataki o rọrun awọn iṣẹyan o ṣeto eyikeyi ipa ati o rọrun ati oṣùpọ ni aro kan ti o mọ o lori ọdọ ti o dara julọ ati ti a gbajumo lati kọ orisirisi itumo agbeka ti o dara julọ ni ifẹjọmọluwabi bernice ni agbara ti o ni lati ṣe iṣẹ pataki ati lati fi awọn ohun ti o nilo jẹ ohun ti o nilo o ni idanwo lati rin lati ọrọ ti o dara julọ o yọ iṣẹ ati o pese iranlowo ati irinṣẹ fun awọn ọmọde rẹ agbekẹ ṣiṣẹ ti o dara julọ fi ti oṣẹ lati pese ayaṣe ati lati ki awọn ọmọde rẹ ma jẹ ifẹran ni iwadi ti o dara julọ awọn ti o nilo ifẹran ti o jẹ ohun ti o ni ọrọ awọn iṣẹ to dara julọ ti o jẹ irinṣẹ iṣẹ ati idagbasoke bernice ni idagbasoke lati fi awọn aṣayan ti o dara julọ fun awọn iṣẹyan rẹ o ni idanwo lati wo awọn iṣẹ mejeeji ati lati fi awọn iṣẹ ti o nilo si awọn ifẹfẹ agbeka rẹ ti o dara julọ lati jẹ irinṣẹ fun awọn iṣẹ ti o si ọkan ninu awọn iṣẹyan o ti dara julọ lori iṣẹṣe iṣẹṣe ati awọn iṣẹyan ti o dara julọ pẹlu agbara iṣẹ ti o dara julọ ati lati fi owo ri bernice jẹ ọmọ alaboyun kan ti o dara julọ ti o dara julọ ati ti o ni adayeba o jẹ abajade to dara julọ o jẹ ọmọ kanlati gba awọn ọmọde rẹ lati dide lọ ati lati se afẹfẹ ni awọn iṣẹyan rẹ |
african leadership university african leadership university alu jẹ iṣẹ iranti to da lori igbala awọn alaboyun ti o wulo ni afrika nipa irinṣẹ ti o ni lati pese iṣẹdọmu ti o dara julọ alu fi awọn olori iṣẹrọ ifunni ati ojogbon lori iṣẹ ti o nilo fun wọn lati fi gba iṣẹsi aye ti o wulo ni afrika si awọn alaboyun iṣẹdọmu ti o dara julọ ti alu jẹ iranti ti o ma n rinrin iṣẹ ati iṣẹda pẹlu iṣẹsẹ ati ifarahun alaboyun lati ṣe iṣẹ afara ti o wulo ni awọn ile-iwe ati nipa ojojumọ kan ni afrika alu ni ipinlẹ ti o mọ pe ni afrika ni gbogbo inu ẹnu ti awọn ọmọde ni ifẹ si jẹ idunnu ati lati ṣe iṣẹ tirẹ lati ṣeto fun iwa kan ti o wulo ni afrika nipa awọn iforukọsilẹ to dara julọ ati awọn iṣẹdọmu ti o wulo alu ti ṣe ọpọlọpọ alaboyun lati ṣe olori idasile ati olori-iranlowo ti o le fi iṣẹ wa ṣe ati lilo aye yii alu ni oṣere nipa awọn iṣẹdọmu ile-iwe ti o wulo ni ilera ti o le wa ni awọn ẹrọ oṣelu ti o gbẹkẹle awọn akọle ti o wa fun awọn iṣẹ ti o nilo ninu afunfun iṣẹ iṣẹ idagbasoke iṣẹkun ati bee ni iwadi ti o nilo fun alaboyun jẹ asopọ ti o ni awọn asopọ pupọ ati awọn ohun ti o nilo fun wọn ti o wẹwẹ lori iṣẹmọ ti o wulo ni afrika |
christopher gwabin musa ọ̀gágun major general christopher gwabin musa tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1967 jẹ́ ọ̀gágun-àgbà tí ó ga jùlọ fún ààbò orílẹ̀-èdè nigeria ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ kàdúná sùgbọ́n tí wọ́n bí sí sokoto ààrẹ bọlá ahmed tinubu ni ó yàn án gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun-àgbà tí ó ga jùlọ fún ààbò orílẹ̀-èdè nigeria lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹfà ọdún 2023 lẹ́yìn tí ààrẹ pàṣẹ láti yọ àwọn ọ̀gágun àgbà tí wọ́n ga jùlọ lẹ́nu iṣẹ́ |
kayode egbetokun kayode egbetokun tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án ọdún 1964 jẹ́ ọ̀gá-àgbà ọ̀lọ́pàá yànyàn ọmọ ìpínlẹ̀ ògùn lórílẹ̀-èdè nigeria ààrẹ bọlá ahmed tinubu ni ó yàn án lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹfà ọdún 2023 láti rọ́pò ọ̀gá-àgbà ọ̀lọ́pàá yàn yàn-àná usman alkali baba lẹ́yìn tí ó kéde yíyọ ọ́ kúrò nípò lọ́jọ́ kan náà ọ̀gá ọ̀lọ́pàá àgbà-yànyàn káyọ̀dé ẹgbẹ́tókùn dára pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ọ̀lọ́pàá gẹ́gẹ́ bí cadet asp lọ́jọ́ kẹta oṣù kẹta ọdún 1990 ó kàwé gboyè bachelor nínú imọ̀ ìsirò ní ilé-ìwé ifáfitì ìjọba àpapọ̀ ti ìlú èkó university of lagos ní ilé-ìwé yẹn bákan náà ó kàwé gboyè bachelor kan náà nínú lámèyító ìmò-ẹ̀rọ engineering analysis àti ìmò okoòwò ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ó sì kàwé gboyè ọ̀mọ̀wé phd nínú ìmọ̀ ìwàlálàáfíà àti ìpètùsáwọ̀ ní ifáfitì al-hikmah university ní ìlú ìlọrin ní ìpínlẹ̀ kwara |
taoreed lagbaja 23rd chief of army staff nigeria ọ̀gágun major general taoreed abíọ́dún lágbájá ni wọ́n bí lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 1968 jẹ́ ọ̀gágun-àgbà tí ó gboyè major general nínú iṣẹ́ ológun orílẹ̀ - èdè nigeria òun ni ọ̀gágun-àgbà yányán àwọn ológun nigeria chief of army staff he was appointed on 19 june 2023 by president bola tinubu to succeed lieutenant general faruk yahaya ìgbà èwe rẹ̀ wọ́n bí lágbájá ní ìlú ìlobù ní ìjọba ìbílẹ̀ ìrẹ́pọ̀dùn ní ìpínlẹ̀ ọ̀sun lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 1968 ó lo ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ ní ìlú òṣogbo níbi tí ó ti kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní ilé-ìwé st charles grammar school and local authority teachers college iṣẹ́ wọ́n gbà á sí ilé-ìwé àwọn ológun nigerian defence academy ọdún 1987 wọ́n fún un lóye ológun second lieutenant lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1992 ẹgbẹ́ ológun nigerian infantry corps |
alex oti alex otti jẹ̀ gómìnà ìpínlẹ̀ abia o dii gómìnà ní ìdìbò gbogbogbò nii ọdún 2023 ní abẹ ẹgbẹ labour |
agbu kefas jẹ́ olóṣèlú nàìjíríà àti olóṣèlú nàìjíríà tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ taraba láti ọdún 2023 |
abba kabir yusuf a bi abba kabir yusuf ni ojo karun osu kinni odun 1963 o je oloselu naijiria to je gomina ipinle kano ni odun 2023 o sise gege bi komisanna ti igbimo alase ni ipinle kano lati odun 2011 si 2015 |
dauda lawal ojoibi 2 osu kesan odun 1965 je okunrin banki ati oloselu omo naijiria ti o je gomina ipinle zamfara wọ́n dìbò yàn án lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú peoples democratic party pdp nínú ìdìbò gómìnà orílẹ̀-èdè nàìjíríà lọ́dún 2023 tí wọ́n ṣẹ́gun gomina bello matawalle ti ẹgbẹ́ òṣèlú apc |
alifabeeti oduduwa alifabeeti odùduwà ni won da lati ko èdè yorùbá ni odun 2017 o ti wa ni igbega ni mejeji nàìjíríà ati benin awọn lẹta ti alifabeeti awọn nọmba |
alifabeeti |
alfabeti |
isaiah oghenevwegba ogedegbe isaiah oghenevwegba ogedegbe ojoibi 14 osu kefa 1991 je omo orile-ede naijiria ti o n se elesin ati oluso buloogi awon asotele ogedegbe jo nipa orile-ede naa awon asotele ogedegbe tun je nipa aare orile-ede naijiria tele ogedegbe ni buloogi kan ti won n pe ni warri times buloogi naa ni ogedegbe ti n ko nkan ati ewi nipa awon eniyan olokiki atejade ogedegbe nipa joseph ayọ́ babalọlá lo gbogun ti ori ero ayelujara o wa ninu akosile pe isaiah ogedegbe pe iku t b joshua ni adanu nla si kristianiti lohin ti o ku ni odun 2021 o tun wa ninu igbasile pe isaiah ogedegbe yin igbesi aye t b joshua ni june 13 2023 ijajagbara ojo kokanla osu keje odun 2014 ni oruko isaiah ogedegbe wa ninu iroyin nigba to ko oriki nipa kefee ni ojo merindinlogun osu keji odun 2018 oruko isaiah ogedegbe tun wa ninu iroyin nigba ti o gba kemi omololu-olunloyo nimoran ni ojo 9 osu kefa odun 2020 oruko isaiah ogedegbe tun wa ninu iroyin nigba ti o ofintoto pipa george floyd ni ojo 29 osu kesan odun 2022 isaiah ogedegbe ko oriki kan lati yin igbe aye nelson mandela ariyanjiyan a ti lo awon asotele isaiah ogedegbe laisi oruko ra ni ojo 27 osu keji odun 2017 ijabo kan nipaso warri times kede aran ti plagiarism kan ni ojo 3 osu kefa odun 2023 isaiah ogedegbe ofintoto plagiarism o si apejuwe bi ole jija ni ojo kokandinlogbon osu keta odun 2023 isaiah ogedegbe gba awon odo naijiria lamoran lati sora fun ohun ti won n gbe jade sori ero ayelujara paapaa nipa bola tinubu ijo re ati iwaasun isaiah ogedegbe ni oludasile ati alabojuto gbogbogbo ti god's prevailing kingdom ministry eyiti o da ni ojo 12 osu kini odun 2020 ni warri jije eniyan ti olorun pe lati waasu isaiah ogedegbe lo buloogi re lati ko awon iwaasu re ti o wa ninu liloye ofiisi anabi ati pelu lori obinrin ati owo igbesi aye ikoko oghara-iyede ti o wa ni ijoba ibile isoko north ni ipinle delta naijiria ni abule isaiah ogedegbe ti wa o si je omo isoko o ti ni iyawo ati pe o ngbe ni warri ipinle delta naijiria arakunrin re ti o dagba ju u ni stewart ogedegbe awon itokasi yi ni a kukuru article jọwọ mu yi |
bako ni lati rii dapo ilesa to daura 1 ounjẹ ẹran ara ti awọn ohun ọsin wa ko ni itumọ bi tiwa wọn ko jẹun ko ni tito nkan lẹsẹsẹ tẹlẹ nipasẹ itọ ni ifun kukuru ati pe o le jiya lati isanraju ti wọn ba jẹ aijẹunnuwọnnu ti o ni idi ti o ṣe pataki lati mọ awọn aini gidi ti aja rẹ lati jẹ ki o ni ilera ọjọ ori aja puppy osu 1-12 awọn iru-ọmọ kekere awọn ọran idagba iyara pupọ ati iwulo fun agbara ati eto ajẹsara ti o lagbara esi ijẹẹmu pataki awọn ọra ati awọn ọlọjẹ / awọn antioxidants diẹ sii fun eto ajẹsara puppy osu 12-18/24 fun awọn ajọbi nla awọn iṣoro idagbasoke ilọsiwaju laisi eewu ere iwuwo iyara tabi kalisiomu pupọ idagbasoke gigun = awọn oṣu 24 idahun ijẹẹmu pataki ipese pipe ti kalisiomu ati irawọ owurọ ni ibamu si iwọn aja aja agba odun kan ati ju bẹẹ lọ awọn iru-ọmọ kekere awọn iṣoro awọn rudurudu ti ounjẹ loorekoore ati awọn iṣoro ehín idahun ijẹẹmu pataki agbara ati ounjẹ ti o ni agbara pupọ / awọn croquettes kekere ti o baamu si iwọn aja / sojurigindin ti ounjẹ / awọn ohun alumọni eyiti o ṣe iranlọwọ lati dinku dida ti tartar aja agba ọdun 2 ati ju bẹẹ lọ fun awọn iru-ọmọ nla awọn iṣoro isẹpo loorekoore ati awọn iṣoro egungun ati awọn iṣoro iwọn apọju esi ijẹẹmu pataki ni awọn nkan lati mu ilọsiwaju ti awọn isẹpo ati akoonu ọra iwọntunwọnsi aja agba lati ọdun 7 awọn iru-ọmọ kekere awọn iṣoro eto ajẹsara ti ko lagbara ati iwọn apọju / awọ ara ati ẹwu ni ipo talaka ati awọn iṣoro ehín idahun ijẹẹmu pataki awọn antioxidants awọn vitamin lati teramo eto ajẹsara / awọn ọlọjẹ lati ṣetọju ibi-iṣan iṣan / omega 3 ati omega 6 fatty acids lati ja lodi si awọn ipa ti ogbo / croquettes fara ni won apẹrẹ ati sojurigindin / din sanra akoonu ati ki o rọrun a iná sanra aja agba lati ọdun 7 fun awọn ajọbi nla awọn iṣoro osteoarthritis idahun ijẹẹmu pataki ni awọn nkan ninu lati mu ilọsiwaju resistance apapọ lati pese awọn idahun ti o tọ si awọn iwulo ijẹẹmu wọnyi yan ounjẹ didara to gaju kibbles - ounjẹ pipe ti a ṣeduro nipasẹ awọn alamọdaju - esi ijẹẹmu ti o baamu si gbogbo awọn iwulo ti aja kọọkan - lilo irọrun ati iwọn lilo irọrun - a dara owo-išẹ ratio awọn ojutu ounjẹ miiran ko ni anfani lati pese gbogbo awọn idahun ijẹẹmu pataki wọnyi nitootọ awọn apoti ko ṣakoso lati pese awọn ounjẹ to ṣe pataki si iwọntunwọnsi to dara ti aja niti ohun ti a pe ni ounjẹ titun ko to ni gbogbogbo nitori pe o nilo lati jẹ iwọn lilo ni ọna ti o ni oye pupọ lati di ounjẹ ilera ati iwọntunwọnsi ojutu pipe julọ jẹ ounjẹ ni irisi awọn croquettes ijẹẹmu didara to gaju yoo gba ọ laaye lati fun aja rẹ ohun gbogbo ti o nilo lati gbe daradara ati ọjọ ori daradara ṣakoso awọn ẹranko rẹ lori r'oko tropical 2 ni abojuto ti aja rẹ ° oju ati eti ninu o gbọdọ tọju awọn agbegbe meji wọnyi ni pataki nitori pe wọn ṣe iranlọwọ fun idagbasoke awọn germs yẹra fun lilo omi fun iru mimọ yii ṣugbọn fẹ awọn ipara/ọja ti ph ti o sunmọ ti aja rẹ ° paadi ati claws - nigbagbogbo ṣayẹwo ipo ti awọn paadi aja rẹ ki o ge irun ti o dagba nibẹ nitootọ awọn paadi naa jẹ ifarabalẹ pupọ ati pe o tun ni itara si abscesses ati awọn akoran olu ni irú ti ikolu kan si alagbawo rẹ veterinarian - idagba ti claw ni iyara o le pari si atunse ati ipalara aja rẹ ni ipele ti paadi naa eyi ni idi ti o ṣe pataki pupọ pe ki o ranti lati ge awọn claws rẹ ti aja rẹ ba gbe diẹ ni otitọ rin ni ọna ti o dara julọ lati wọ awọn claws kukuru wọn yoo ran aja rẹ lọwọ lati lọ kiri ati ki o ṣe idiwọ fun u lati ni ipalara ° awọ ati irun fọ aja rẹ nigbagbogbo lati yọ irun ti o ku ati idoti kuro idagba ti ẹwu naa yoo jẹ irọrun awọn igbohunsafẹfẹ ti brushing da lori awọn eya si eyi ti rẹ aja je ti kukuru gun lile dan irun… ti aja rẹ ba ni kukuru tabi gun irun brushing yẹ ki o wa ojoojumọ ti aja rẹ ba jẹ gigun-alabọde woolly tabi kukuru-irun aja brushing yẹ ki o ṣee ṣe lẹẹkan tabi lẹmeji ni ọsẹ kan wẹ aja rẹ nigbagbogbo ṣugbọn ṣọra botilẹjẹpe igbohunsafẹfẹ ti iwẹ da lori ijade ọsin rẹ ati awọn iṣere ere igbohunsafẹfẹ yatọ lati ọsẹ 2 si 6 maṣe wẹ nigbagbogbo nitori pe ninu ọran yii sebum aabo ti ẹwu rẹ ti yọkuro ati ipa igbona rẹ ti yipada yan kan pato shampulu ti o ni agbara giga ti kii ṣe ibinu ti o bọwọ fun ph aja rẹ ti yoo daabobo awọ ara rẹ daradara maṣe lo shampulu rẹ ṣugbọn nigbagbogbo shampulu kan pato fun awọn aja nitori aja rẹ ni ph ti o yatọ pupọ si tirẹ yago fun awọn shampulu gbigbẹ ti o ni opin iṣẹ ṣiṣe mimọ ṣakoso awọn ẹranko rẹ lori r'oko tropical |
darlington nwokocha darlington nwokocha jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ó jẹ́ asójú agbègbè abia central federal láti ọdún 2023 kí ó tó di sénátọ̀ ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmò asofin kékeré tí ó sójú isiala-ngwa north/isiala-ngwa south láàrin 2015 sí 2019 nwokocha jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ abia state house of assembly láàrin 2007 sí 2015 |
ishaku abbo ishaku elisha abbo tí a bí ní mubi north nàìjíríà jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun ni sénátọ̀ tí ó ń ṣe aṣojú àgbègbè adamawa north senatorial district ní ìpínlẹ̀ adamawa ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú all progressives congress apc lọ́wọ́ lọ́wọ́ ipa rẹ̀ nínú òsèlú ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kejì ọdún 2019 wọ́n yan abbo gẹ́gẹ́ bi sénátọ̀ tí ó ń sójú agbègbè apá àríwá adamawa iye àwọn tí ó dìbò fun tó 79337 |
binos dauda yaroe sen binos dauda yaroe jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà àti sénátọ̀ tí ó ń sójú agbègbè adamawa south senatorial district ti ìpínlẹ̀ adamawa ní ilé ìgbìmò aṣòfin àgbà lọ́wọ́lọ́wọ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀ wọ́n bí binos dauda yaroe ní ọjọ́ kínní oṣù kínní ọdún 1955 ní wagole abúlé kan ní agbègbè ribadu ward ti ìjọba ìbílè mayo-belwa ní ìpínlẹ̀ adámáwá nàìjíríà ó fẹ́ mrs gimbiya joshua ní ọdún 1983 wọ́n bí ọmọ mẹ́rin |
gwagwalada gwagwalada jẹ́ ọ̀kan lára àwọn íjọba ìbílẹ̀ ní federal capital territory orílẹ̀ èdè nàìjíríà gwagwalada ní ilẹ̀ tí ó tó 1043 km2 àti olùgbé 157770 ní ìgbà ìkànìyàn ti ọdún 2006 kí wọ́n wọ́n tó dá gwagwalada kalẹ̀ ó wà lábẹ́ agbègbè kwali ti abuja tẹ́lẹ̀ |
abidi braille awọn abidi braille jẹ eto kikọ fun afọju ti a fi ọwọ ka awọn abidi braille wa fun ọpọlọpọ awọn ede pẹlu èdè yorùbá lẹta awọn lẹta ti alifabeeti |
Subsets and Splits